Neh 13 YCE

Yíyẹra Kúrò lára Àwọn Àjèjì

1 LI ọjọ na, a kà ninu iwe Mose li eti gbogbo enia, ati ninu rẹ̀ li a ri pe, ki ara Ammoni ati ara Moabu ki o má wá sinu ijọ Ọlọrun lailai;

2 Nitoriti nwọn kò fi onjẹ ati omi ko awọn ọmọ Israeli lọna, ṣugbọn nwọn bẹ̀ Balaamu lọwẹ si wọn, lati fi wọn gegun: ṣugbọn Ọlọrun wa sọ egun na di ibukun.

3 O si ṣe, nigbati nwọn ti gbọ́ ofin na, ni nwọn yà gbogbo awọn ọ̀pọ enia ti o darapọ̀ mọ Israeli kuro.

Àtúnṣe Tí Nehemiah ṣe

4 Ati ṣaju eyi, Eliaṣibu alufa, ti o jẹ alabojuto iyẹwu ile Ọlọrun wa jẹ ana Tobiah.

5 O si ti pèse iyẹwu nla kan fun u, nibiti nwọn ima fi ẹbọ ohun jijẹ, turari, ati ohun èlo, ati idamẹwa agbado, ọti-waini titun, ati ororo si nigba atijọ, eyi ti a pa li aṣẹ lati fi fun awọn ọmọ Lefi, ati awọn akọrin, ati awọn adèna: ati ẹbọ ọrẹ awọn alufa.

6 Ṣugbọn ni gbogbo àkoko yi, emi kò si ni Jerusalemu: nitori li ọdun kejilelọgbọn ti Artasasta ọba Babiloni, mo wá si ọdọ ọba, ati li opin ọjọ wọnni, mo gba àye lati ọdọ ọba.

7 Mo si wá si Jerusalemu, mo si mọ̀ buburu ti Eliaṣibu ṣe nitori Tobiah, ni pipèse iyẹwu fun u, ninu àgbala ile Ọlọrun.

8 O si bà mi ninu jẹ gidigidi, nitorina mo da gbogbo ohun èlo Tobiah jade kuro ninu iyẹwu na.

9 Nigbana ni mo paṣẹ, nwọn si wẹ̀ iyẹwu na mọ: si ibẹ ni mo si tun mu ohun èlo ile Ọlọrun wá, pẹlu ẹbọ ohun jijẹ ati turari.

10 Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀.

11 Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn.

12 Nigbana ni gbogbo Juda mu idamẹwa ọka ati ọti-waini titun ati ororo wá si ile iṣura.

13 Mo si yàn olupamọ si ile iṣura, Ṣelemiah alufa ati Sadoku akọwẹ, ati ninu awọn ọmọ Lefi, Pedaiah: ati lọwọkọwọ wọn ni Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah: nitoriti a kà wọn si olõtọ, iṣẹ́ wọn si ni lati ma pin fun awọn arakunrin wọn.

14 Ranti mi, Ọlọrun mi, nitori eyi, ki o má si nu iṣẹ rere ti mo ti ṣe fun ile Ọlọrun mi, nu kuro, ati fun akiyesi rẹ̀.

15 Li ọjọ wọnni ni mo ri awọn kan ti nfunti ni Juda li ọjọ isimi, awọn ti nmu iti ọka wale, ti ndi ẹrù rù kẹtẹkẹtẹ; ti ọti-waini, pẹlu eso àjara, ati eso ọ̀pọtọ, ati gbogbo oniruru ẹrù ti nwọn nmu wá si Jerusalemu li ọjọ isimi: mo si jẹri gbè wọn li ọjọ ti nwọn ntà ohun jijẹ.

16 Awọn ara Tire ngbe ibẹ pẹlu, ti nwọn mu ẹja, ati oniruru ohun èlo wá, nwọn si ntà li ọjọ isimi fun awọn ọmọ Juda, ati ni Jerusalemu.

17 Nigbana ni mo ba awọn ijoye Juda jà, mo si wi fun wọn pe, ohun buburu kili ẹnyin nṣe yi, ti ẹ si mba ọjọ isimi jẹ.

18 Bayi ha kọ́ awọn baba nyin ṣe, Ọlọrun kò ha mu ki gbogbo ibi yi wá sori wa, ati sori ilu yi? ṣugbọn ẹnyin mu ibinu ti o pọ̀ju wá sori Israeli nipa biba ọjọ isimi jẹ.

19 O si ṣe, nigbati ẹnu-bode Jerusalemu bẹ̀rẹ si iṣu okunkun ṣaju ọjọ isimi, mo paṣẹ pe, ki a tì ilẹkun, ki ẹnikẹni má ṣi i titi di ẹhin ọjọ isimi, ninu awọn ọmọkunrin mi ni mo fi si ẹnu-bode, ki a má ba mu ẹrù wọle wá li ọjọ isimi.

20 Bẹ̃ni awọn oniṣòwo ati awọn ti ntà oniruru nkan sùn lẹhin odi Jerusalemu li ẹrinkan tabi ẹrinmeji.

21 Nigbana ni mo jẹri gbè wọn, mo si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi sùn lẹhin odi, bi ẹnyin ba tun ṣe bẹ̃, emi o fọwọ bà nyin. Lati àkoko na lọ ni nwọn kò si wá lọjọ isimi mọ.

22 Mo si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ya ara wọn si mimọ, ki nwọn si wa ṣọ ẹnu-bode lati pa ọjọ isimi mọ. Ranti mi Ọlọrun mi nitori eyi pẹlu, ki o si da mi si gẹgẹ bi ọ̀pọ ãnu rẹ.

23 Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, mo ri ara Juda ti mba obinrin awọn ara Aṣdodi, Ammoni, ati ti Moabu gbe:

24 Awọn ọmọ wọn si nsọ apakan ède Aṣdodi, nwọn kò si le sọ̀rọ li ède awọn ara Juda, ṣugbọn gẹgẹ bi ède olukuluku.

25 Mo si ba wọn jà, mo gàn wọn, mo lù ninu wọn, mo tu irun wọn, mo mu wọn fi Ọlọrun bura pe, Ẹnyin kì yio fi ọmọbinrin nyin fun ọmọkunrin nwọn, tabi ọmọbinrin nwọn fun ọmọkunrin nyin tabi fun ara nyin.

26 Solomoni ọba Israeli kò ha dẹṣẹ nipa nkan wọnyi? Bẹ̃ni li ãrin orilẹ-ède pupọ, kò si ọba kan bi on ti Ọlọrun rẹ̀ fẹràn; Ọlọrun si fi jẹ ọba li ori gbogbo Israeli, bẹ̃ni on li awọn àjeji obinrin mu ki o ṣẹ̀.

27 Njẹ ki awa ha gbọ́ ti nyin, lati ṣe gbogbo buburu nla yi, lati ṣẹ̀ si Ọlọrun sa, ni gbigbe awọn àjeji obinrin ni iyawo?

28 Ati ọkan ninu awọn ọmọ Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olori alufa, jẹ ana Sanballati, ara Horoni, nitori na mo le e kuro lọdọ mi.

29 Ranti wọn, Ọlọrun mi, nitoriti nwọn ti ba oyè alufa jẹ, pẹlu majẹmu oyè-alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi.

30 Bayi ni mo wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo awọn alejo, mo si yan ẹ̀ṣọ awọn alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi, olukuluku ninu iṣẹ tirẹ̀.

31 Ati fun ẹ̀bun igi li àkoko ti a yàn, ati fun akọso. Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13