Neh 3 YCE

Títún Ògiri Jerusalẹmu Mọ

1 NIGBANA ni Eliaṣibu olori alufa dide pẹlu awọn alufa arakunrin rẹ̀, nwọn si mọ ẹnu-bode agutan; nwọn sọ ọ di mimọ́, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ duro, titi de ile-iṣọ Mea, ni nwọn sọ di mimọ́ titi de ile-iṣọ Hananeeli.

2 Lọwọkọwọ rẹ̀ ni awọn ọkunrin Jeriko si mọ: lọwọkọwọ wọn ni Sakkuri ọmọ Imri si mọ.

3 Ṣugbọn ẹnu-bode Ẹja ni awọn ọmọ Hasenaa mọ, ẹniti o tẹ́ igi idabu rẹ̀, ti o si gbe ilẹkun rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀.

4 Lọwọkọwọ wọn ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi, tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Sadoku, ọmọ Baana tun ṣe.

5 Ati lọwọkọwọ wọn ni awọn ará Tekoa tun ṣe, ṣugbọn awọn ọlọla kò fi ọrùn si iṣẹ Oluwa wọn.

6 Jehoida, ọmọ Pasea, ati Meṣullamu, ọmọ Besodiah, si tun ẹnu-bode atijọ ṣe, nwọn tẹ̀ igi idabu rẹ̀, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, ati àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀.

7 Lọwọkọwọ wọn ni Melatiah, ará Gibeoni, tun ṣe, ati Jadoni, ara Merono, awọn ọkunrin ti Gibeoni, ati ti Mispa, ti o jẹ ti itẹ bãlẹ̀ apa ihin odò.

8 Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Ussieli ọmọ Harhiah, alagbẹdẹ wura tun ṣe; ati lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hananiah ọmọ alapolu, tun ṣe; nwọn si ti fi Jerusalemu silẹ̀ titi de odi gbigbõro.

9 Lọwọkọwọ wọn ni Refaiah, ọmọ Huri ijòye idaji Jerusalemu si tun ṣe.

10 Lọwọkọwọ wọn ni Jedaiah, ọmọ Haramafu, si tun ṣe, ani ọkánkan ile rẹ̀. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hattuṣi ọmọ Haṣabaniah si tun ṣe.

11 Malkijah ọmọ Harimu, ati Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu, tun apa keji ṣe, ati ile-iṣọ ileru.

12 Ati lọwọkọwọ rẹ̀ Ṣallumu ọmọ Haloheṣi, ijòye apa kan Jerusalemu, tun ṣe, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀.

13 Hanuni pẹlu awọn ará Sanoa si tun ẹnu-bode afonifoji ṣe; nwọn kọ́ ọ, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itikùn rẹ̀, ati ẹgbẹrun igbọnwọ odi titi de ẹnu-bode ãtàn.

14 Ẹnu-bode ãtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, ijòye apa kan Bet-hakkeremu tun ṣe; o kọ́ ọ, o gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itìkun rẹ̀.

15 Ṣallumu, ọmọ Kol-hose, ijòye apakan Mispa si tun ẹnu-bode orisun ṣe; o kọ́ ọ, o si bò o, o si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itìkun rẹ̀ ati odi adagun Ṣiloa li ẹ̀ba ọgba ọba, ati titi de atẹ̀gun ti o sọkalẹ lati ile Dafidi lọ.

16 Lẹhin rẹ̀ ni Nehemiah, ọmọ Asbuku, ijòye idaji Bet-huri, tun ṣe titi de ibi ọkánkán iboji Dafidi, ati de adagun ti a ṣe, ati titi de ile awọn alagbara.

Àwọn Ọmọ Lefi tí Wọ́n Ṣiṣẹ́ ní Ibi Odi náà

17 Lẹhin rẹ̀ ni awọn ọmọ Lefi, Rehumu, ọmọ Bani tun ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Haṣabiah ijòye idaji Keila tun ṣe li apa tirẹ̀.

18 Lẹhin rẹ̀ ni awọn arakunrin wọn tun ṣe, Bafai ọmọ Henadadi, ijoye idaji Keila.

19 Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, ijòye Mispa, tun apa miran ṣe li ọkánkán titọ lọ si ile-ihamọra kọrọ̀ odi.

20 Lẹhin rẹ̀ ni Baruku ọmọ Sabbai fi itara tun apa miran ṣe, lati igun ogiri titi de ilẹkùn ile Eliaṣibu, olori alufa.

21 Lẹhin rẹ̀ ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi tun apa miran ṣe lati ilẹkùn ile Eliaṣibu titi de ipẹkun ile Eliaṣibu.

22 Lẹhin rẹ̀ ni awọn alufa si tun ṣe, awọn ọkunrin pẹtẹlẹ [Jordani].

23 Lẹhin wọn ni Benjamini ati Haṣubu tun ṣe li ọkánkán ile wọn. Lẹhin wọn ni Asariah ọmọ Maasiah ọmọ Ananiah tun ṣe lẹba ile rẹ̀.

24 Lẹhin rẹ̀ ni Binnui, ọmọ Henadadi tun apa miran ṣe, lati ile Asariah titi de igun odi, ani titi de kọrọ̀.

25 Palali ọmọ Usai li ọkánkán igun odi, ati ile-iṣọ ti o yọ sode lati ile giga ti ọba wá ti o wà lẹba ile tubu. Lẹhin rẹ̀ ni Padaiah ọmọ Paroṣi.

26 Ṣugbọn awọn Netinimu gbe Ofeli, titi de ọkánkán ẹnu-bode omi niha ila-õrùn ati ile iṣọ ti o yọ sode.

Àwọn Mìíràn tí Wọ́n Tún Ṣiṣẹ́ níbi Odi náà

27 Lẹhin wọn ni awọn ara Tekoa tun apa miran ṣe, li ọkánkán ile-iṣọ nla ti o yọ sode, titi de odi Ofeli.

28 Lati oke ẹnu-bode ẹṣin ni awọn alufa tun apa miran ṣe, olukuluku li ọkánkán ile rẹ̀.

29 Lẹhin wọn ni Sadoku, ọmọ Immeri tun ṣe li ọkánkán ile rẹ̀: lẹhin rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùtọju ẹnubode ila-õrùn tun ṣe.

30 Lẹhin wọn ni Hananiah ọmọ Selamiah tun ṣe, ati Hanuni ọmọ Salafu kẹfa tun apa miran ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah li ọkánkán yàra rẹ̀.

31 Lẹhin rẹ̀ ni Malkiah ọmọ alagbẹdẹ wura tun ṣe, titi de ile awọn Netinimu ati ti awọn oniṣòwo, li ọkánkán ẹnu bode Mifkadi ati yàra òke igun-odi.

32 Ati larin yàra òke igun-odi titi de ẹnu-bode agutan ni awọn alagbẹdẹ wura ati awọn oniṣòwo tun ṣe.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13