1 O SI ṣe, nigbati a mọ odi na tan, ti mo si gbe ilẹkùn ro, ti a si yan awọn oludena ati awọn akọrin, ati awọn ọmọ Lefi,
2 Mo si fun Hanani arakunrin mi, ati Hananiah ijòye ãfin, li aṣẹ lori Jerusalemu: nitori olododo enia li o ṣe, o si bẹ̀ru Ọlọrun jù enia pupọ lọ.
3 Mo si wi fun wọn pe, Ẹ má jẹ ki ilẹkùn odi Jerusalemu ṣi titi õrùn o fi mú; bi nwọn si ti duro, jẹ ki wọn se ilẹkùn, ki nwọn si há wọn, ki nwọn si yan ẹ̀ṣọ ninu awọn ti ngbe Jerusalemu, olukuluku ninu iṣọ rẹ̀, ati olukuluku ninu ile rẹ̀.
4 Ṣugbọn ilu na gbõrò, o si tobi, awọn enia inu rẹ̀ si kere, a kò si kọ́ ile tan.
5 Ọlọrun mi si fi si mi li ọkàn lati ko awọn ijòye jọ, ati awọn olori, ati awọn enia, ki a le kà wọn nipa idile wọn. Mo si ri iwe idile awọn ti o kọ́ goke wá, mo ri pe, a kọ ọ sinu rẹ̀.
6 Wọnyi ni awọn ọmọ igberiko, ti o gòke wá lati ìgbekun ninu awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnesari ọba Babiloni ti ko lọ, ti nwọn tun padà wá si Jerusalemu, ati si Juda, olukuluku si ilu rẹ̀.
7 Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemia, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordikai, Bilṣani, Mispereti, Bigfai, Nehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin enia Israeli li eyi;
8 Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbã o le mejilelãdọsan.
9 Awọn ọmọ Ṣefatiah, ojidinirinwo o le mejila.
10 Awọn ọmọ Ara, adọtalelẹgbẹta o le meji.
11 Awọn ọmọ Pahat-moabu, ti awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejidilogun.
12 Awọn ọmọ Elamu, ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.
13 Awọn ọmọ Sattu, ojilelẹgbẹrin o le marun.
14 Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin.
15 Awọn ọmọ Binnui, ojilelẹgbẹta o le mẹjọ.
16 Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mejidilọgbọn.
17 Awọn ọmọ Asgadi, egbejila o di mejidilọgọrin.
18 Awọn ọmọ Adonikamu ọtalelẹgbẹta o le meje.
19 Awọn ọmọ Bigfai, ẹgbã o le mẹtadilãdọrin.
20 Awọn ọmọ Adini, ãdọtalelẹgbẹta o le marun.
21 Awọn ọmọ Ateri, ti Hesekiah mejidilọgọrun.
22 Awọn ọmọ Haṣamu, ọrindinirinwo o le mẹjọ.
23 Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹrin.
24 Awọn ọmọ Harifu mejilelãdọfa.
25 Awọn ọmọ Gibioni, marundilọgọrun.
26 Awọn ọkunrin Betlehemu ati Netofa, ọgọsan o le mẹjọ.
27 Awọn ọkunrin Anatoti, mejidilãdoje.
28 Awọn ọkunrin Bet-asmafeti, mejilelogoji.
29 Awọn ọkunrin Kiriat-jearimu, Kefira, ati Beeroti, ọtadilẹgbẹrin o le mẹta,
30 Awọn ọkunrin Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun.
31 Awọn ọkunrin Mikmasi, mejilelọgọfa.
32 Awọn ọkunrin Beteli ati Ai, mẹtalelọgọfa.
33 Awọn ọkunrin Nebo miran mejilelãdọta.
34 Awọn ọmọ Elamu miran ẹgbẹfa o le mẹrinlelãdọta.
35 Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.
36 Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.
37 Awọn ọmọ Lodi, Hadidi, ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le ọkan.
38 Awọn ọmọ Senaah ẹgbãji o di ãdọrin.
39 Awọn alufa: awọn ọmọ Jedaiah ti ile Jeṣua, ẹgbã o di mẹtadilọgbọn.
40 Awọn ọmọ Immeri, ẹgbẹrun o le mejilelãdọta.
41 Awọn ọmọ Paṣuri, ẹgbẹfa o le mẹtadiladọta.
42 Awọn ọmọ Harimu ẹgbẹrun o le mẹtadilogun.
43 Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua, ti Kadmieli, ninu ọmọ Hodafa, mẹrinlelãdọrin.
44 Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdọjọ.
45 Awọn oludena: awọn ọmọ Ṣallumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, mejidilogoje.
46 Awọn ọmọ Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Haṣufa, awọn ọmọ Tabbaoti,
47 Awọn ọmọ Kerosi, awọn ọmọ Sia, awọn ọmọ Padoni,
48 Awọn ọmọ Lebana, awọn ọmọ Hagaba, awọn ọmọ Salmai,
49 Awọn ọmọ Hanani, awọn ọmọ Giddeli, awọn ọmọ Gahari,
50 Awọn ọmọ Reaiah, awọn ọmọ Resini, awọn ọmọ Nekoda,
51 Awọn ọmọ Gassamu, awọn ọmọ Ussa, awọn ọmọ Fasea,
52 Awọn ọmọ Besai, awọn ọmọ Meunimu, awọn ọmọ Nefiṣesimu,
53 Awọn ọmọ Bakbuku, awọn ọmọ Hakufa, awọn ọmọ Harhuri,
54 Awọn ọmọ Basliti, awọn ọmọ Mehida, awọn ọmọ Harsa,
55 Awọn ọmọ Barkosi, awọn ọmọ Sisera, awọn ọmọ Tama,
56 Awọn ọmọ Nesia, awọn ọmọ Hatifa.
57 Awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni: awọn ọmọ Sotai, awọn ọmọ Sofereti, awọn ọmọ Perida,
58 Awọn ọmọ Jaala, awọn ọmọ Darkoni, awọn ọmọ Giddeli,
59 Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Amoni.
60 Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni jẹ irinwo din mẹjọ.
61 Awọn wọnyi li o si goke lati Telhariṣa, Kerubu, Addoni, ati Immeri wá: ṣugbọn nwọn kò le fi ile baba wọn hàn, tabi iran wọn, bi nwọn iṣe ti Israeli.
62 Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ojilelẹgbẹta ole meji.
63 Ati ninu awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Kosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o ni ọkan ninu awọn ọmọbinrin Barsillai, ara Gileadi, li aya, a si npè e nipa orukọ wọn.
64 Awọn wọnyi wá iwe orukọ wọn ninu awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn nipa idile ṣugbọn a kò ri i: nitorina li a ṣe yà wọn kurò ninu oyè alufa.
65 Bãlẹ na si wi fun wọn pe, ki nwọn máṣe jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi duro pẹlu Urimu, ati Tummimu,
66 Iye gbogbo ijọ jasi ẹgbãmọkanlelogun o le ojidinirinwo.
67 Laikà awọn iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹ-binrin wọn, iye wọn jẹ ẹgbẹtadilẹgbãrin o di ẹtalelọgọta: nwọn si ni ojilugba o le marun akọni ọkunrin ati akọni obinrin.
68 Ẹṣin wọn jẹ ọtadilẹgbẹrin o di mẹrin: ibaka nwọn jẹ ojilugba o le marun:
69 Rakumi jẹ ojilenirinwo o di marun: kẹtẹkẹtẹ jẹ ẹgbẹrinlelọgbọn o di ọgọrin.
70 Omiran ninu awọn olori ninu awọn baba fi nkan si iṣẹ na. Bãlẹ fi ẹgbẹrun dramu wura, ãdọta awokoto, ọrindilẹgbẹta le mẹwa ẹwu alufa sinu iṣura na.
71 Ninu awọn olori ninu awọn baba fi ọkẹ meji dramu wura, ati ẹgbọkanla mina fadaka si iṣura iṣẹ na.
72 Ati eyiti awọn enia iyokù mu wá jẹ ọkẹ meji dramu wura, ati ẹgbã mina fadaka, ati ẹwu alufa mẹtadilãdọrin.
73 Bẹ̃ni awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn oludena, ati awọn akọrin, ati ninu awọn enia, ati awọn Netinimu, ati gbogbo Israeli, ngbe ilu wọn; nigbati oṣu keje si pé, awọn ọmọ Israeli wà ni ilu wọn.