34 Awa si dìbo larin awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ati awọn enia, fun ọrẹ igi, lati mu u wá si ile Ọlọrun wa, gẹgẹ bi idile awọn baba wa li akoko ti a yàn li ọdọdun, lati fi daná li ori pẹpẹ Oluwa Ọlọrun wa, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin.
35 Ati lati mu akọso ilẹ wa wá, ati gbogbo akọso eso igi gbogbo, li ọdọdun si ile Oluwa wa:
36 Pẹlu akọbi awọn ọmọ wa ọkunrin, ati ti ohun ọ̀sin wa, gẹgẹ bi ati kọ ninu ofin, akọbi awọn ẹran-nla wa, ati ti agutan wa, lati mu wọn wá si ile Ọlọrun wa, fun awọn alufa ti nṣiṣẹ ni ile Ọlọrun wa.
37 Ki awa si mu akọso iyẹfun pipò wa wá, ati ọrẹ wa, ati eso oniruru igi wa, ti ọti-waini ati ti ororo fun awọn alufa, si iyẹwu ile Ọlọrun wa, ati idamẹwa ilẹ wa fun awọn ọmọ Lefi, ki awọn ọmọ Lefi ki o le ni idamẹwa ninu gbogbo ilu arọko wa.
38 Alufa ọmọ Aaroni yio si wà pẹlu awọn ọmọ Lefi, nigbati awọn ọmọ Lefi yio gba idamẹwa: awọn ọmọ Lefi yio si mu idamẹwa ti idamẹwa na wá si ile Ọlọrun wa, sinu iyẹwu, sinu ile iṣura.
39 Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Lefi ni yio mu ọrẹ ọkà wá, ti ọti-waini titun, ati ororo, sinu iyẹwu, nibiti ohun èlo ibi mimọ́ gbe wà, ati awọn alufa ti nṣiṣẹ, ati awọn adèna, ati awọn akọrin: awa kì yio si kọ̀ ile Ọlọrun wa silẹ.