6 Emi si binu gidigidi nigbati mo gbọ́ igbe wọn ati ọ̀rọ wọnyi.
7 Mo si ronu ọ̀ran na, mo si ba awọn ijoye ati awọn olori wi, mo si wi fun wọn pe, Ẹnyin ngba ẹdá olukuluku lọwọ arakunrin rẹ̀. Mo si pe apejọ nla tì wọn.
8 Mo si wi fun wọn pe, Awa nipa agbara wa ti rà awọn ara Juda arakunrin wa padà, ti a tà fun awọn keferi; ẹnyin o ha si mu ki a tà awọn arakunrin nyin? tabi ki a ha tà wọn fun wa? Nwọn si dakẹ, nwọn kò ri nkankan dahùn.
9 Mo si wi pẹlu pe, Ohun ti ẹ ṣe kò dara: kò ha yẹ ki ẹ ma rìn ninu ìbẹru Ọlọrun wa, nitori ẹgan awọn keferi ọta wa?
10 Emi pẹlu, ati awọn arakunrin mi, ati awọn ọmọkunrin mi, nyá wọn ni owó ati ọkà, ẹ jẹ ki a pa èlé gbígbà yí tì.
11 Mo bẹ̀ nyin, ẹ fi oko wọn, ọgbà-ajarà wọn, ọgbà-olifi wọn, ati ile wọn, ida-ọgọrun owo na pẹlu, ati ti ọkà, ọti-waini, ati ororo wọn, ti ẹ fi agbara gbà, fun wọn padà loni yi.
12 Nwọn si wipe, Awa o fi fun wọn pada, awa kì yio si bere nkankan lọwọ wọn; bẹ̃li awa o ṣe bi iwọ ti wi. Nigbana ni mo pe awọn alufa, mo si mu wọn bura pe, nwọn o ṣe gẹgẹ bi ileri yi.