1 O SI ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati Geṣemu, ara Arabia, ati awọn ọta wa iyokù, gbọ́ pe, mo ti mọ odi na, ati pe, kò kù ibi yiya kan ninu rẹ̀, (bi emi kò tilẹ iti gbe ilẹkùn wọnni ro ni ibode li akoko na;)
2 Ni Sanballati ati Geṣemu ranṣẹ si mi, wipe, Wá, jẹ ki a jọ pade ninu ọkan ninu awọn ileto ni pẹtẹlẹ Ono. Ṣugbọn nwọn ngbero ati ṣe mi ni ibi.
3 Mo si ran onṣẹ si wọn pe, Emi nṣe iṣẹ nla kan, emi kò le sọkalẹ wá: ẽṣe ti iṣẹ na yio fi duro nigbati mo ba fi i silẹ, ti mo ba si sọkalẹ tọ̀ nyin wá?
4 Sibẹ nwọn ranṣẹ si mi nigba mẹrin bayi; mo si da wọn lohùn bakanna.