11 Mo si wipe, Enia bi emi a ma sa? Tali o si dabi emi, ti o jẹ wọ inu tempili lọ lati gba ẹmi rẹ̀ là? Emi kì yio wọ̀ ọ lọ.
12 Sa kiyesi i, mo woye pe, Ọlọrun kò rán a, ṣugbọn pe, o nsọ asọtẹlẹ yi si mi: nitori Tobiah ati Sanballati ti bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ.
13 Nitorina li o ṣe bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ, ki emi ba foya, ki emi ṣe bẹ̃, ki emi si ṣẹ̀, ki nwọn le ri ihìn buburu rò, ki nwọn le kẹgàn mi.
14 Ọlọrun mi, rò ti Tobiah ati Sanballati gẹgẹ bi iṣẹ wọn wọnyi, ati ti Noadiah, woli obinrin, ati awọn woli iyokù ti nwọn fẹ mu mi bẹ̀ru,
15 Bẹ̃li a pari odi na li ọjọ kẹ̃dọgbọn oṣù Eluli, ni ọjọ mejilelãdọta.
16 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọta wa gbọ́, gbogbo awọn keferi àgbegbe wa si bẹ̀ru, nwọn si rẹ̀wẹsi pupọ li oju ara wọn, nitori nwọn woye pe, lati ọwọ Ọlọrun wá li a ti ṣe iṣẹ wọnyi.
17 Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, awọn ijòye Juda ran iwe pupọ si Tobiah, iwe Tobiah si de ọdọ wọn.