2 Ni Sanballati ati Geṣemu ranṣẹ si mi, wipe, Wá, jẹ ki a jọ pade ninu ọkan ninu awọn ileto ni pẹtẹlẹ Ono. Ṣugbọn nwọn ngbero ati ṣe mi ni ibi.
3 Mo si ran onṣẹ si wọn pe, Emi nṣe iṣẹ nla kan, emi kò le sọkalẹ wá: ẽṣe ti iṣẹ na yio fi duro nigbati mo ba fi i silẹ, ti mo ba si sọkalẹ tọ̀ nyin wá?
4 Sibẹ nwọn ranṣẹ si mi nigba mẹrin bayi; mo si da wọn lohùn bakanna.
5 Nigbana ni Sanballati rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mi bakanna nigba karun ti on ti iwe ṣíṣi lọwọ rẹ̀.
6 Ninu rẹ̀ li a kọ pe, A nrohin lãrin awọn keferi, Gaṣimu si wi pe, iwọ ati awọn ara Juda rò lati ṣọ̀tẹ: nitori idi eyi ni iwọ ṣe mọ odi na, ki iwọ le jẹ ọba wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi.
7 Iwọ pẹlu si ti yan awọn woli lati kede rẹ ni Jerusalemu wipe, Ọba wà ni Juda: nisisiyi ni a o si rò o fun ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Njẹ wá nisisiyi, ki a jọ gbimọ̀ pọ̀.
8 Nigbana ni mo ranṣẹ si i wipe, A kò ṣe iru eyi, ti iwọ sọ, ṣugbọn iwọ rò wọn li ọkàn ara rẹ ni.