5 Ọlọrun mi si fi si mi li ọkàn lati ko awọn ijòye jọ, ati awọn olori, ati awọn enia, ki a le kà wọn nipa idile wọn. Mo si ri iwe idile awọn ti o kọ́ goke wá, mo ri pe, a kọ ọ sinu rẹ̀.
6 Wọnyi ni awọn ọmọ igberiko, ti o gòke wá lati ìgbekun ninu awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnesari ọba Babiloni ti ko lọ, ti nwọn tun padà wá si Jerusalemu, ati si Juda, olukuluku si ilu rẹ̀.
7 Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemia, Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordikai, Bilṣani, Mispereti, Bigfai, Nehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin enia Israeli li eyi;
8 Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbã o le mejilelãdọsan.
9 Awọn ọmọ Ṣefatiah, ojidinirinwo o le mejila.
10 Awọn ọmọ Ara, adọtalelẹgbẹta o le meji.
11 Awọn ọmọ Pahat-moabu, ti awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejidilogun.