4 Nigbana ni Jeṣua, ati Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani ati Kenani duro lori pẹtẹsì awọn ọmọ Lefi, nwọn si fi ohun rara kigbe si Oluwa Ọlọrun wọn.
5 Awọn ọmọ Lefi, Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣabaiah, Ṣerebiah, Hodijah, Sebaniah, ati Pelaniah, si wipe: Ẹ dide, ki ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin lai ati lailai: ibukun si ni fun orukọ rẹ ti o li ogo, ti o ga jù gbogbo ibukun ati iyìn lọ.
6 Iwọ, ani iwọ nikanṣoṣo li Oluwa; iwọ li o ti dá ọrun, ọrun awọn ọrun pẹlu gbogbo ogun wọn, aiye, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ̀ ninu rẹ̀, iwọ si pa gbogbo wọn mọ́ lãyè, ogun ọrun si nsìn ọ.
7 Iwọ ni Oluwa Ọlọrun, ti o ti yan Abramu, ti o si mu u jade lati Uri ti Kaldea wá, iwọ si sọ orukọ rẹ̀ ni Abrahamu;
8 Iwọ si ri pe ọkàn rẹ̀ jẹ olõtọ niwaju rẹ, iwọ si ba a dá majẹmu lati fi ilẹ awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Amori, ati awọn ara Perisi, ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Girgasi fun u, lati fi fun iru-ọmọ rẹ̀, iwọ si ti mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ; nitori olododo ni iwọ:
9 Iwọ si ri ipọnju awọn baba wa ni Egipti, o si gbọ́ igbe wọn lẹba Okun Pupa;
10 O si fi ami, ati iṣẹ-iyanu hàn li ara Farao, ati li ara gbogbo iranṣẹ rẹ̀, ati li ara gbogbo enia ilẹ rẹ̀: nitori iwọ mọ̀ pe, nwọn hu ìwa igberaga si wọn. Iwọ si fi orukọ fun ara rẹ bi ti oni yi.