1 LI oṣù kẹjọ, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah wá, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli, pe,
2 Oluwa ti binu pupọ̀ si awọn baba nyin.
3 Nitorina iwọ wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ yipadà si mi, emi o si yipadà si nyin, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
4 Ẹ má dàbi awọn baba nyin, awọn ti awọn woli iṣãju ti ké si wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Ẹ yipadà nisisiyi kuro li ọ̀na buburu nyin, ati kuro ninu ìwa-buburu nyin: ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò fetisi ti emi, ni Oluwa wi.
5 Awọn baba nyin, nibo ni nwọn wà? ati awọn woli, nwọn ha wà titi aiye?