4 Lati ọdọ rẹ̀ ni igun ti jade wá, lati ọdọ rẹ̀ ni iṣo ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni ọrun ogun ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni awọn akoniṣiṣẹ gbogbo ti wá.
5 Nwọn o si dabi awọn alagbara, ti ntẹ́ ẹrẹ̀ ita ni mọlẹ li ogun: nwọn o si jagun, nitori Oluwa wà pẹlu wọn nwọn o si doju tì awọn ti ngùn ẹṣin.
6 Emi o si mu ile Juda le, emi o si gbà ile Josefu là, emi o si tún mu wọn joko; nitori mo ti ṣãnu fun wọn, nwọn o si dabi ẹnipe emi kò ti ta wọn nù: nitori emi ni Oluwa Ọlọrun wọn, emi o si gbọ́ ti wọn.
7 Efraimu yio si ṣe bi alagbara, ọkàn wọn yio si yọ̀ bi ẹnipe nipa ọti-waini: ani awọn ọmọ wọn yio ri i, nwọn o si yọ̀, inu wọn o si dùn si Oluwa.
8 Emi o kọ si wọn, emi o si ṣà wọn jọ; nitori emi ti rà wọn pada: nwọn o si rẹ̀ si i gẹgẹ bi wọn ti nrẹ̀ si i ri.
9 Emi o si gbìn wọn lãrin awọn enia: nwọn o si ranti mi ni ilẹ jijin; nwọn o si wà pẹlu awọn ọmọ wọn, nwọn o si tún pada.
10 Emi o si tún mu wọn pada kuro ni ilẹ Egipti pẹlu, emi o si ṣà wọn jọ kuro ni ilẹ Assiria: emi o si mu wọn wá si ilẹ Gileadi ati Lebanoni; a kì yio si ri àye fun wọn.