6 Emi o si mu ile Juda le, emi o si gbà ile Josefu là, emi o si tún mu wọn joko; nitori mo ti ṣãnu fun wọn, nwọn o si dabi ẹnipe emi kò ti ta wọn nù: nitori emi ni Oluwa Ọlọrun wọn, emi o si gbọ́ ti wọn.
7 Efraimu yio si ṣe bi alagbara, ọkàn wọn yio si yọ̀ bi ẹnipe nipa ọti-waini: ani awọn ọmọ wọn yio ri i, nwọn o si yọ̀, inu wọn o si dùn si Oluwa.
8 Emi o kọ si wọn, emi o si ṣà wọn jọ; nitori emi ti rà wọn pada: nwọn o si rẹ̀ si i gẹgẹ bi wọn ti nrẹ̀ si i ri.
9 Emi o si gbìn wọn lãrin awọn enia: nwọn o si ranti mi ni ilẹ jijin; nwọn o si wà pẹlu awọn ọmọ wọn, nwọn o si tún pada.
10 Emi o si tún mu wọn pada kuro ni ilẹ Egipti pẹlu, emi o si ṣà wọn jọ kuro ni ilẹ Assiria: emi o si mu wọn wá si ilẹ Gileadi ati Lebanoni; a kì yio si ri àye fun wọn.
11 Yio si là okun wahala ja, yio si lù riru omi ninu okun, gbogbo ibu odò ni yio si gbẹ, a o si rẹ̀ igberaga Assiria silẹ, ọpa alade Egipti yio si lọ kuro.
12 Emi o si mu wọn le ninu Oluwa; nwọn o si rìn soke rìn sodò li orukọ rẹ̀, ni Oluwa wi.