2 Kiye si i, emi o sọ Jerusalemu di ago iwarìri si gbogbo enia yika, nigbati nwọn o do tì Juda ati Jerusalemu.
3 Li ọjọ na li emi o sọ Jerusalemu di ẹrù okuta fun gbogbo enia: gbogbo awọn ti o ba si fi dẹrù pa ara wọn li a o ke si wẹwẹ, bi gbogbo awọn orilẹ-ède aiye tilẹ ko ara wọn jọ si i.
4 Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o fi itagìri lù gbogbo ẹṣin, ati fi wère lu ẹniti ngùn u; emi o si ṣi oju mi si ile Juda, emi o si bu ifọju lù gbogbo ẹṣin ti enia na.
5 Ati awọn bãlẹ Juda yio si wi li ọkàn wọn pe, Awọn ara Jerusalemu li agbara mi nipa Oluwa Ọlọrun wọn.
6 Li ọjọ na li emi o ṣe awọn bãlẹ Juda bi ãrò iná kan lãrin igi, ati bi ètùfù iná lãrin ití; nwọn o si jẹ gbogbo awọn enia run yika lapa ọ̀tun ati lapa osi: a o si tun ma gbe Jerusalemu ni ipo rẹ̀, ani Jerusalemu.
7 Oluwa pẹlu yio kọ́ tète gba agọ Juda là na, ki ogo ile Dafidi ati ogo awọn ara Jerusalemu ma bà gbe ara wọn ga si Juda.
8 Li ọjọ na li Oluwa yio dãbò bò awọn ti ngbe Jerusalemu; ẹniti o ba si ṣe ailera ninu wọn li ọjọ na yio dabi Dafidi; ile Dafidi yio si dabi Ọlọrun, bi angeli Oluwa niwaju wọn.