1 NIGBANA ni mo yipadà, mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, iwe-kiká ti nfò.
2 O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Emi si dahùn pe, mo ri iwe-kiká ti nfò; gigùn rẹ̀ jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ igbọnwọ mẹwa.
3 O si wi fun mi pe, Eyi ni ègun ti o jade lọ si gbogbo ilẹ aiye: nitori gbogbo awọn ti o ba jale ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀; gbogbo awọn ti o ba si bura ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀.
4 Emi o mu u jade, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, yio si wọ̀ inu ile olè lọ, ati inu ile ẹniti o ba fi orukọ mi bura eke: yio si wà li ãrin ile rẹ̀, yio si run u pẹlu igi ati okuta inu rẹ̀.
5 Angeli ti mba mi sọ̀rọ si jade lọ, o si wi fun mi pe, Gbe oju rẹ si oke nisisiyi, ki o si wò nkan yi ti o jade lọ.