6 Mo si wipe, Kini nì? O si wipe, Eyi ni òṣuwọn efà ti o jade lọ. O si wipe, Eyi ni àworan ni gbogbo ilẹ aiye.
7 Si kiyesi i, a gbe talenti ojé soke: obinrin kan si niyi ti o joko si ãrin òṣuwọn efa.
8 O si wipe, Eyi ni ìwa-buburu. O si jù u si ãrin òṣuwọn efa: o si jù òṣuwọn ojé si ẹnu rẹ̀.
9 Mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, obinrin meji jade wá, ẹfũfu si wà ninu iyẹ wọn; nitori nwọn ni iyẹ bi iyẹ àkọ: nwọn si gbe òṣuwọn efa na de agbedemeji aiye on ọrun.
10 Mo si sọ fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ pe, Nibo ni awọn wọnyi ngbe òṣuwọn efa na lọ?
11 O si wi fun mi pe, Lati kọ́ ọ ni ile ni ilẹ Ṣinari: a o si fi idi rẹ̀ mulẹ, a o si fi ka ori ipilẹ rẹ̀ nibẹ̀.