1 MO si yipadà, mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, kẹkẹ́ mẹrin jade wá lati ãrin oke-nla meji; awọn oke-nla na si jẹ oke-nla idẹ.
2 Awọn ẹṣin pupa wà ni kẹkẹ́ ekini; ati awọn ẹṣin dudu ni kẹkẹ́ keji;
3 Ati awọn ẹṣin funfun ni kẹkẹ́ kẹta; ati awọn adikalà ati alagbara ẹṣin ni kẹkẹ́ kẹrin.
4 Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti mba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi, oluwa mi?
5 Angeli na si dahùn o si wi fun mi pe, Wọnyi ni awọn ẹmi mẹrin ti ọrun, ti njade lọ kuro ni iduro niwaju Oluwa gbogbo aiye.
6 Awọn ẹṣin dudu ti o wà ninu rẹ̀ jade lọ si ilẹ ariwa; awọn funfun si jade tẹ̀le wọn; awọn adíkalà si jade lọ si ihà ilẹ gusù.
7 Awọn alagbara ẹṣin si jade lọ, nwọn si nwá ọ̀na ati lọ ki nwọn ba le rìn sihin sọhun li aiye; o si wipe, Ẹ lọ, ẹ lọ irìn sihin sọhun li aiye. Nwọn si rìn sihin sọhun li aiye.