7 Awọn alagbara ẹṣin si jade lọ, nwọn si nwá ọ̀na ati lọ ki nwọn ba le rìn sihin sọhun li aiye; o si wipe, Ẹ lọ, ẹ lọ irìn sihin sọhun li aiye. Nwọn si rìn sihin sọhun li aiye.
8 Nigbana ni on si kọ́ si mi, o si ba mi sọ̀rọ, wipe, Wò o, awọn wọnyi ti o lọ sihà ilẹ ariwa ti mu ẹmi mi parọrọ ni ilẹ ariwa.
9 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
10 Mu ninu igbèkun, ninu awọn ti Heldai, ti Tobijah, ati ti Jedaiah, ti o ti Babiloni de, ki iwọ si wá li ọjọ kanna, ki o si wọ ile Josiah ọmọ Sefaniah lọ;
11 Ki o si mu fàdakà ati wurà, ki o si fi ṣe ade pupọ̀, ki o si gbe wọn kà ori Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa:
12 Si sọ fun u pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Wò ọkunrin na ti orukọ rẹ̀ njẹ ẸKA; yio si yọ ẹka lati abẹ rẹ̀ wá, yio si kọ́ tempili Oluwa;
13 On ni yio si kọ́ tempili Oluwa; on ni yio si rù ogo, yio si joko yio si jọba lori itẹ rẹ̀; on o si jẹ alufa lori itẹ̀ rẹ̀; ìmọ alafia yio si wà lãrin awọn mejeji.