7 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Kiye si i, emi o gbà awọn enia mi kuro ni ilẹ ila-õrun, ati kuro ni ilẹ yama;
8 Emi o si mu wọn wá, nwọn o si ma gbe ãrin Jerusalemu: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, li otitọ, ati li ododo.
9 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Jẹ ki ọwọ nyin ki o le, ẹnyin ti ngbọ́ ọ̀rọ wọnyi li ọjọ wọnyi li ẹnu awọn woli ti o wà li ọjọ ti a fi ipilẹ ile Oluwa awọn ọmọ-ogun lelẹ, ki a ba le kọ́ tempili.
10 Nitori pe ṣãju ọjọ wọnni ọya enia kò to nkan, bẹni ọ̀ya ẹran pẹlu; bẹ̃ni kò si alafia fun ẹniti njade lọ, tabi ẹniti nwọle bọ̀, nitori ipọnju na: nitori mo doju gbogbo enia olukuluku kọ aladugbo rẹ̀.
11 Ṣugbọn nisisiyi emi kì yio ṣe si iyokù awọn enia yi gẹgẹ bi ti ìgba atijọ wọnni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
12 Nitori irugbin yio gbilẹ: àjara yio so eso rẹ̀, ilẹ yio si hù ọ̀pọlọpọ nkan rẹ̀ jade, awọn ọrun yio si mu irì wọn wá: emi o si mu ki awọn iyokù enia yi ni gbogbo nkan wọnyi.
13 Yio si ṣe, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ egún lãrin awọn keferi, ẹnyin ile Juda, ati ile Israeli, bẹ̃li emi o gbà nyin silẹ; ẹnyin o si jẹ ibukún: ẹ má bẹ̀ru, ṣugbọn jẹ ki ọwọ nyin ki o le.