3 Tire si mọ odi lile fun ara rẹ̀, o si ko fàdakà jọ bi ekuru, ati wurà daradara bi ẹrẹ̀ ita.
4 Kiye si i, Oluwa yio tá a nù, yio si kọlu ipá rẹ̀ ninu okun; a o si fi iná jẹ ẹ run.
5 Aṣkeloni yio ri i, yio si bẹ̀ru; Gasa pẹlu yio ri i, yio si kãnu gidigidi, ati Ekroni: nitori oju o tì ireti rẹ̀: ọba yio si ṣegbe kuro ni Gasa, a kì o si gbe Aṣkeloni.
6 Ọmọ alè yio si gbe inu Aṣdodi, emi o si ke irira awọn Filistini kuro.
7 Emi o si mu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro li ẹnu rẹ̀, ati ohun irira rẹ̀ wọnni kuro lãrin ehín rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o kù, ani on na yio jẹ ti Ọlọrun wa, yio si jẹ bi bãlẹ kan ni Juda, ati Ekroni bi Jebusi.
8 Emi o si dó yi ilẹ mi ka nitori ogun, nitori ẹniti nkọja lọ, ati nitori ẹniti npada bọ̀: kò si aninilara ti yio là wọn já mọ: nitori nisisiyi ni mo fi oju mi ri.
9 Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ.