1 TEOFILU, ìhìn iṣaju ni mo ti rò, niti ohun gbogbo ti Jesu bẹ̀rẹ si iṣe, ati si ikọ́,
2 Titi o fi di ọjọ ti a gbà a lọ soke, lẹhin ti o ti ti ipa Ẹmi Mimọ́ paṣẹ fun awọn aposteli ti o yàn:
3 Awọn ẹniti o si farahàn fun lãye lẹhin ìjiya rẹ̀ nipa ẹ̀rí pupọ ti o daju, ẹniti a ri lọdọ wọn li ogoji ọjọ ti o nsọ ohun ti iṣe ti ijọba Ọlọrun:
4 Nigbati o si ba wọn pejọ, o paṣẹ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe kuro ni Jerusalemu, ṣugbọn ki nwọn ki o duro dè ileri Baba, eyiti, o wipe, ẹnyin ti gbọ́ li ẹnu mi:
5 Nitori nitotọ ni Johanu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin, kì iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ.