Iṣe Apo 27 YCE

Paulu Wọkọ̀ Lọ sí Romu

1 Bi a si ti pinnu rẹ̀ pe ki a wọ̀ ọkọ lọ si Itali, nwọn fi Paulu, ati awọn ondè miran kan pẹlu, le balogun ọrún kan lọwọ, ti a npè ni Juliu, ti ẹgbẹ ọmọ-ogun Augustu.

2 Nigbati a si wọ̀ ọkọ̀ Adramittiu kan, ti nfẹ lọ si awọn ilu ti o wà leti okun Asia, awa ṣikọ̀: Aristarku, ara Makedonia ti Tessalonika, wà pẹlu wa.

3 Ni ijọ keji awa de Sidoni. Juliu si ṣe inu rere si Paulu, o si bùn u láye ki o mã tọ̀ awọn ọrẹ́ rẹ̀ lọ lati ri itọju.

4 Nigbati awa si ṣikọ̀ nibẹ̀, awa lọ lẹba Kipru, nitoriti afẹfẹ ṣọwọ òdi.

5 Nigbati awa ré okun Kilikia on Pamfilia kọja, awa de Mira Likia.

6 Nibẹ̀ ni balogun ọrún si ri ọkọ̀ Aleksandria kan, ti nlọ si Itali; o si fi wa sinu rẹ̀.

7 Nigbati awa nlọ jẹ́jẹ li ọjọ pipọ, ti awa fi agbara kaka de ọkankan Knidu, ti afẹfẹ kò bùn wa làye, awa lọ lẹba Krete, li ọkankan Salmone;

8 Nigbati a si fi agbara kaka kọja rẹ̀, awa de ibi ti a npè ni Ebute Yiyanjú, ti o sunmọ ibiti ilu Lasea ti wà ri.

9 Nigbati a si ti sọ ọjọ pipọ nù, ti a-ti ta igbokun wa idi ewu tan, nitori Awẹ ti kọja tan, Paulu da imọran,

10 O si wi fun wọn pe, Alàgba, mo woye pe iṣikọ̀ yi yio li ewu ati òfo pipọ, kì iṣe kìki ti ẹrù ati ti ọkọ̀, ṣugbọn ti ẹmí wa pẹlu.

11 Ṣugbọn balogun ọrún gbà ti olori ọkọ̀ ati ti ọlọkọ̀ gbọ́, jù ohun wọnni ti Paulu wi lọ.

12 Ati nitori ebute na kò rọrùn lati lo akoko otutu nibẹ̀, awọn pipọ si damọran pe, ki a lọ kuro nibẹ̀, bi nwọn ó le làkàka de Fenike lati lo akoko otutu, ti iṣe ebute Krete ti o kọju si òsi ìwọ õrùn, ati ọtún ìwọ õrùn.

Ìjì Jà ní Òkun

13 Nigbati afẹfẹ gusù si nfẹ jẹ́jẹ, ti nwọn ṣebi ọwọ awọn tẹ̀ ohun ti nwọn nwá, nwọn ṣikọ̀, nwọn npá ẹba Krete lọ.

14 Kò si pẹ lẹhin na ni ìji ti a npè ni Eurakuilo fẹ lù u.

15 Nigbati o si ti gbé ọkọ̀, ti kò si le dojukọ ìji na, awa jọwọ rẹ̀, o ngbá a lọ.

16 Nigbati o si gbá a lọ labẹ erekuṣu kan ti a npè ni Klauda, o di iṣẹ pipọ ki awa ki o to le sunmọ igbaja.

17 Nigbati nwọn si gbé e soke, nwọn nṣe iranlọwọ, nwọn ndì ọkọ ni isalẹ; nigbati nwọn si bẹ̀ru ki a ma ba gbá wọn sori iyanrìn diẹ̀, nwọn tagbokun, nwọn si ngbá kiri.

18 Bi awa si ti nṣe lãlã gidigidi ninu ìji na, ni ijọ keji nwọn kó nkan dà si omi lati mu ọkọ̀ fẹrẹ;

19 Ati ni ijọ kẹta, a fi ọwọ́ ara wa kó ohun èlo ọkọ̀ danu.

20 Nigbati õrùn ati irawọ kò si hàn li ọjọ pipọ, ti ìji na kò si mọ̀ niwọn fun wa, abá a-ti-là kò si fun wa mọ́.

21 Nigbati nwọn wà ni aijẹun li ọjọ pipọ, nigbana Paulu dide larin wọn, o ni, Alàgba, ẹnyin iba ti gbọ́ ti emi, ki a máṣe ṣikọ̀ kuro ni Krete, ewu ati òfo yi kì ba ti ba wa.

22 Njẹ nisisiyi mo gbà nyin niyanju, ki ẹ tújuka: nitori kì yio si òfo ẹmí ninu nyin, bikoṣe ti ọkọ̀.

23 Nitori angẹli Ọlọrun, ti ẹniti emi iṣe, ati ẹniti emi nsìn, o duro tì mi li oru aná,

24 O wipe, Má bẹ̀ru, Paulu; iwọ kò le ṣaima duro niwaju Kesari: si wo o, Ọlọrun ti fi gbogbo awọn ti o ba ọ wọkọ̀ pọ̀ fun ọ.

25 Njẹ nitorina, alàgba, ẹ daraya: nitori mo gbà Ọlọrun gbọ́ pe, yio ri bẹ̃ gẹgẹ bi a ti sọ fun mi.

26 Ṣugbọn a ó gbá wa jù si erekuṣu kan.

27 Ṣugbọn nigbati o di oru ijọ kẹrinla, ti awa ngbá sihin sọhún ni Adria, larin ọganjọ awọn atukọ̀ tànmã pe, awọn sunmọ eti ilẹ kan;

28 Nigbati nwọn si wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn li ogún àgbaká: nigbati nwọn si sún siwaju diẹ, nwọn si tún wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn ni àgbaká mẹ̃dogun.

29 Nigbati nwọn bẹ̀ru ki nwọn ki o máṣe gbá lù ibi okuta, nwọn sọ idakọró mẹrin silẹ ni idi ọkọ̀, nwọn nreti ojumọ́.

30 Ṣugbọn nigbati awọn atukọ̀ nwá ọ̀na ati sá kuro ninu ọkọ̀, ti nwọn si ti sọ igbaja kalẹ si oju okun bi ẹnipe nwọn nfẹ sọ idakọró silẹ niwaju ọkọ̀,

31 Paulu wi fun balogun ọrún ati fun awọn ọmọ-ogun pe, Bikoṣepe awọn wọnyi ba duro ninu ọkọ̀ ẹnyin kì yio le là.

32 Nigbana li awọn ọmọ-ogun ke okùn igbaja, nwọn jọwọ rẹ̀ ki o ṣubu sọhún.

33 Nigbati ilẹ nmọ́ bọ̀, Paulu bẹ̀ gbogbo wọn ki nwọn ki o jẹun diẹ, o wipe, Oni li o di ijẹrinla ti ẹnyin ti nreti, ti ẹ kò dẹkun gbãwẹ, ti ẹ kò si jẹun.

34 Nitorina mo bẹ̀ nyin, ki ẹ jẹun diẹ: nitori eyi ni fun igbala nyin: nitori irun kan kì yio re kuro li ori ẹnikan nyin.

35 Nigbati o si wi nkan wọnyi, ti o si mu akara, o dupẹ lọwọ Ọlọrun niwaju gbogbo wọn: nigbati o si bù u, o bẹ̀rẹ si ijẹ.

36 Nigbana ni gbogbo wọn si daraya, awọn pẹlu si gbà onjẹ.

37 Gbogbo wa ti mbẹ ninu ọkọ̀ na si jẹ ọrinlugba ọkàn o dí mẹrin.

38 Nigbati nwọn jẹun yó tan, nwọn kó nkan danù kuro ninu ọkọ̀, nwọn si kó alikama dà si omi.

Ọkọ̀ Rì

39 Nigbati ilẹ si mọ, nwọn kò mọ̀ ilẹ na: ṣugbọn nwọn ri apa odò kan ti o li ebute, nibẹ̀ ni nwọn gbero, bi nwọn o ba le tì ọkọ̀ si.

40 Nigbati nwọn si ké idakọró kuro, nwọn jọ̀wọ wọn sinu okun, lẹsẹkanna nwọn tu ide ọkọ̀, nwọn si ta igbokun iwaju ọkọ̀ si afẹfẹ, nwọn wa kọju si ilẹ.

41 Nigbati nwọn si de ibiti okun meji pade, nwọn fi ori ọkọ̀ sọlẹ; iwaju rẹ̀ si kàn mọlẹ ṣinṣin, o duro, kò le yi, ṣugbọn agbara riru omi bẹrẹ si fọ́ idi ọkọ̀ na.

42 Ero awọn ọmọ-ogun ni ki a pa awọn onde, ki ẹnikẹni wọn ki o má ba wẹ̀ jade sá lọ.

43 Ṣugbọn balogun ọrún nfẹ gbà Paulu là, o kọ̀ ero wọn; o si paṣẹ fun awọn ti o le wẹ̀ ki nwọn ki o kọ́ bọ si okun lọ si ilẹ,

44 Ati awọn iyokù, omiran lori apako, ati omiran lori ẹfọkọ̀. Bẹ̃li o si ṣe ti gbogbo wọn yọ, li alafia de ilẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28