Iṣe Apo 11 YCE

Peteru Ròhìn fún Ìjọ ní Jerusalẹmu

1 AWỌN aposteli ati awọn arakunrin ti o wà ni Judea si gbọ́ pe awọn Keferi pẹlu ti gba ọ̀rọ Ọlọrun.

2 Nigbati Peteru si gòke wá si Jerusalemu, awọn ti ikọla mba a sọ,

3 Wipe, Iwọ wọle tọ̀ awọn enia alaikọlà lọ, o si ba wọn jẹun.

4 Ṣugbọn Peteru bẹ̀rẹ si ilà a fun wọn lẹsẹsẹ, wipe,

5 Emi wà ni ilu Joppa, mo ngbadura: mo ri iran kan li ojuran, Ohun elo kan sọkalẹ bi gọgọwu nla, ti a ti igun mẹrẹrin sọ̀ ka ilẹ lati ọrun wá; o si wá titi de ọdọ mi:

6 Mo tẹjumọ ọ, mo si fiyesi i, mo si ri ẹran ẹlẹsẹ mẹrin aiye, ati ẹranko igbẹ́, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju ọrun.

7 Mo si gbọ́ ohùn kan ti o fọ̀ si mi pe, Dide, Peteru; mã pa, ki o si mã jẹ.

8 Ṣugbọn mo dahùn wipe, Agbẹdọ, Oluwa: nitori ohun èwọ tabi alaimọ́ kan kò wọ̀ ẹnu mi ri lai.

9 Ṣugbọn ohùn kan dahun lẹ̃keji lati ọrun wá pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ.

10 Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: a sì tun fà gbogbo rẹ̀ soke ọrun.

11 Si wo o, lojukanna ọkunrin mẹta duro niwaju ile ti a gbé wà, ti a rán lati Kesarea si mi.

12 Ẹmí si wi fun mi pe, ki emi ki o ba wọn lọ, ki emi máṣe kọminu ohunkohun. Awọn arakunrin mẹfa wọnyi si ba mi lọ, a si wọ̀ ile ọkunrin na:

13 O si sọ fun wa bi on ti ri angẹli kan ti o duro ni ile rẹ̀, ti o si wipe, Ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni ti apele rẹ̀ jẹ Peteru;

14 Ẹniti yio sọ ọ̀rọ fun ọ, nipa eyiti a o fi gbà iwọ ati gbogbo ile rẹ là.

15 Bi mo si ti bẹ̀rẹ si isọ, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn, gẹgẹ bi o ti bà le wa li àtetekọṣe.

16 Nigbana ni mo ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wipe, Johanu fi omi baptisi nitõtọ; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin.

17 Njẹ bi Ọlọrun si ti fi iru ẹ̀bun kanna fun wọn ti o ti fifun awa pẹlu nigbati a gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, tali emi ti emi ó fi le dè Ọlọrun li ọ̀na?

18 Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́, nwọn si yìn Ọlọrun logo wipe, Njẹ Ọlọrun fi ironupiwada si ìye fun awọn Keferi pẹlu.

Ìjọ ní Antioku

19 Nitorina awọn ti a si tuka kiri niti inunibini ti o ṣẹ̀ niti Stefanu, nwọn rìn titi de Fenike, ati Kipru, ati Antioku, nwọn kò sọ ọ̀rọ na fun ẹnikan, bikoṣe fun kìki awọn Ju.

20 Ṣugbọn awọn kan mbẹ ninu wọn ti iṣe ara Kipru, ati Kirene; nigbati nwọn de Antioku nwọn sọ̀rọ fun awọn Hellene pẹlu, nwọn nwasu Jesu Oluwa.

21 Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu wọn: ọpọlọpọ awọn ti o gbagbọ́ yipada si Oluwa.

22 Ihìn wọn si de etí ijọ ti o wà ni Jerusalemu: nwọn si rán Barnaba lọ titi de Antioku;

23 Ẹniti, nigbati o de ti o si ri õre-ọfẹ Ọlọrun, o yọ̀, o si gba gbogbo wọn niyanju pe, pẹlu ipinnu ọkàn ni ki nwọn ki o fi ara mọ́ Oluwa.

24 Nitori on jẹ enia rere, o si kún fun Ẹmí Mimọ́, ati fun igbagbọ́: enia pipọ li a si kà kún Oluwa.

25 Barnaba si jade lọ si Tarsu lati wá Saulu.

26 Nigbati o si ri i, o mu u wá si Antioku. O si ṣe, fun ọdun kan gbako ni nwọn fi mba ijọ pejọ pọ̀, ti nwọn si kọ́ enia pipọ. Ni Antioku li a si kọ́ pè awọn ọmọ-ẹhin ni Kristian.

27 Li ọjọ wọnni li awọn woli si ti Jerusalemu sọkalẹ wá si Antioku.

28 Nigbati ọkan ninu wọn, ti a npè ni Agabu si dide, o tipa Ẹmi sọ pe, ìyan nla yio mu ká gbogbo aiye: eyiti o si ṣẹ li ọjọ Klaudiu Kesari.

29 Awọn ọmọ-ẹhin si pinnu, olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti to, lati rán iranlọwọ si awọn arakunrin ti o wà ni Judea:

30 Eyiti nwọn si ṣe, nwọn si fi i ranṣẹ si awọn àgba lati ọwọ́ Barnaba on Saulu.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28