1 NIGBATI ọjọ Pentekosti si de, gbogbo nwọn fi ọkàn kan wà nibikan.
2 Lojijì iró si ti ọrun wá, gẹgẹ bi iró ẹ̀fũfu lile, o si kún gbogbo ile nibiti nwọn gbé joko.
3 Ẹla ahọn bi ti iná si yọ si wọn, o pin ara rẹ̀ o si bà le olukuluku wọn.
4 Gbogbo nwọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si bẹ̀rẹ si ifi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wọn li ohùn.
5 Awọn Ju olufọkànsin lati orilẹ-ede gbogbo labẹ ọrun si ngbe Jerusalemu.
6 Nigbati nwọn si gbọ iró yi, ọ̀pọlọpọ enia pejọ, nwọn si damu, nitoriti olukuluku gbọ́ nwọn nsọ̀rọ li ède rẹ̀.
7 Hà si ṣe gbogbo wọn, ẹnu si yà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Wo o, ara Galili ki gbogbo awọn ti nsọ̀rọ wọnyi iṣe?
8 Ẽha si ti ṣe ti awa fi ngbọ́ olukuluku li ede wa ninu eyiti a bí wa?
9 Awọn ará Partia, ati Media, ati Elamu, ati awọn ti ngbé Mesopotamia, Judea, ati Kappadokia, Pontu, ati Asia,
10 Frigia, ati Pamfilia, Egipti, ati ẹkùn Libia niha Kirene, ati awọn atipo Romu, awọn Ju ati awọn alawọṣe Ju,
11 Awọn ara Krete ati Arabia, awa gbọ́ nwọn nsọ̀rọ iṣẹ iyanu nla Ọlọrun li ède wa.
12 Hà si ṣe gbogbo wọn, o si rú wọn lojú, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili a le mọ̀ eyi si?
13 Ṣugbọn awọn ẹlomiran nṣẹ̀fẹ nwọn si wipe, Awọn ọkunrin wọnyi kún fun waini titun.
14 Ṣugbọn Peteru dide duro pẹlu awọn mọkanla iyokù, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o si wi fun wọn gbangba pe, Ẹnyin enia Judea, ati gbogbo ẹnyin ti ngbé Jerusalemu, ki eyiyi ki o yé nyin, ki ẹ si fetísi ọ̀rọ mi:
15 Nitori awọn wọnyi kò mutiyó, bi ẹnyin ti fi pè; wakati kẹta ọjọ sá li eyi.
16 Ṣugbọn eyi li ọ̀rọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joeli wá pe;
17 Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin-ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá:
18 Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obinrin li emi o tú ninu Ẹmí mi jade li ọjọ wọnni; nwọn o si ma sọtẹlẹ:
19 Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn loke li ọrun, ati àmi nisalẹ lori ilẹ: ẹ̀jẹ, ati iná, ati ríru ẹ̃fin;
20 A o sọ õrùn di òkunkun, ati oṣupa di ẹ̀jẹ, ki ọjọ nla afiyesi Oluwa ki o to de:
21 Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba pè orukọ Oluwa, a o gbà a là.
22 Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ wọnyi: Jesu ti Nasareti, ọkunrin ti a fi hàn fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá, nipa iṣẹ agbara ati ti iyanu, ati ti àmi ti Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe lãrin nyin, bi ẹnyin tikaranyin ti mọ̀ pẹlu:
23 Ẹniti a ti fi le nyin lọwọ nipa ipinnu ìmọ ati imọtẹlẹ Ọlọrun; on li ẹnyin mu, ti ẹ ti ọwọ awọn enia buburu kàn mọ agbelebu, ti ẹ si pa.
24 Ẹniti Ọlọrun gbé dide, nigbati o ti tú irora ikú: nitoriti kò ṣe iṣe fun u lati dì i mu.
25 Nitori Dafidi ti wi nipa tirẹ̀ pe, Mo ri Oluwa nigba-gbogbo niwaju mi, nitoriti o mbẹ li ọwọ́ ọtún mi, ki a mà bà ṣí mi ni ipò:
26 Nitorina inu mi dùn, ahọn mi si yọ̀; pẹlupẹlu ara mi yio si simi ni ireti:
27 Nitoriti iwọ ki yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú, bẹ̃ni iwọ ki yio jẹ ki Ẹni-Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ.
28 Iwọ mu mi mọ̀ ọ̀na iye; iwọ ó mu mi kún fun ayọ̀ ni iwaju rẹ.
29 Ará, ẹ jẹ ki emi ki o sọ fun nyin gbangba niti Dafidi baba nla pe, o kú, a si sin i, ibojì rẹ̀ si mbẹ lọdọ wa titi o fi di oni yi.
30 Nitoriti iṣe woli, ati bi o ti mọ̀ pe, Ọlọrun ti fi ibura ṣe ileri fun u pe, Ninu irú-ọmọ inu rẹ̀, on ó mu ọ̀kan ijoko lori itẹ́ rẹ̀;
31 O ri eyi tẹlẹ̀, o sọ ti ajinde Kristi pe, a kò fi ọkàn rẹ̀ silẹ ni ipò-okù, bẹ̃li ara rẹ̀ kò ri idibajẹ.
32 Jesu na yi li Ọlọrun ti ji dide, ẹlẹri eyiti gbogbo wa iṣe.
33 Nitorina bi a ti fi ọwọ́ ọtún Ọlọrun gbe e ga, ti o si ti gbà ileri Ẹmí Mimọ́ lati ọdọ Baba, o tú eyi silẹ, ti ẹnyin ri, ti ẹ si gbọ́.
34 Dafidi kò sá gòke lọ si ọrun: ṣugbọn on tikararẹ̀ wipe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi,
35 Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apotì itisẹ rẹ.
36 Njẹ ki gbogbo ile Israeli ki o mọ̀ dajudaju pe, Ọlọrun ti fi Jesu na, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, jẹ Oluwa ati Kristi.
37 Nigbati nwọn si gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ, nwọn si sọ fun Peteru ati awọn aposteli iyokù pe, Ará, kini ki awa ki o ṣe?
38 Peteru si wi fun wọn pe, Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹ̀ṣẹ nyin, ẹnyin o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ́.
39 Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè.
40 Ati ọ̀rọ pupọ miran li o fi njẹri ti o si nfi ngbà wọn niyanju wipe, Ẹ gbà ara nyin là lọwọ iran arekereke yi.
41 Nitorina awọn ti o si fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ rẹ̀ a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn.
42 Nwọn si duro ṣinṣin ninu ẹkọ́ awọn aposteli, ati ni idapọ, ni bibu akara ati ninu adura.
43 Ẹ̀rù si ba gbogbo ọkàn: iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi pipọ li a ti ọwọ́ awọn aposteli ṣe.
44 Gbogbo awọn ti o si gbagbọ́ wà ni ibikan, nwọn ni ohun gbogbo ṣọkan;
45 Nwọn si ntà ohun ini ati ẹrù wọn, nwọn si npín wọn fun olukuluku, gẹgẹ bi ẹnikẹni ti ṣe alaini.
46 Nwọn si nfi ọkàn kan duro li ojojumọ́ ninu tẹmpili ati ni bibu akara ni ile, nwọn nfi inu didùn ati ọkàn kan jẹ onjẹ wọn.
47 Nwọn nyin Ọlọrun, nwọn si ni ojurere lọdọ enia gbogbo. Oluwa si nyàn kún wọn li ojojumọ awọn ti a ngbalà.