Iṣe Apo 19 YCE

Paulu Dé Efesu

1 O si ṣe, nigbati Apollo ti wà ni Korinti, ti Paulu kọja lọ niha ẹkùn oke, o wá si Efesu: o si ri awọn ọmọ-ẹhin kan;

2 O wi fun wọn pe, Ẹnyin ha gbà Ẹmí Mimọ́ na nigbati ẹnyin gbagbọ́? Nwọn si wi fun u pe, Awa kò gbọ́ rara bi Ẹmí Mimọ́ kan wà.

3 O si wipe, Njẹ baptismu wo li a ha baptisi nyin si? Nwọn si wipe, Si baptismu ti Johanu.

4 Paulu si wipe, Nitõtọ, ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ̀ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu.

5 Nigbati nwọn si gbọ́, a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa.

6 Nigbati Paulu si gbe ọwọ́ le wọn, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn; nwọn si nfọ̀ ède miran, nwọn si nsọ asọtẹlẹ.

7 Iye awọn ọkunrin na gbogbo to mejila.

8 Nigbati o si wọ̀ inu sinagogu lọ, o fi igboiya sọ̀rọ li oṣù mẹta, o nfi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀, o si nyi wọn lọkan pada si nkan ti iṣe ti ijọba Ọlọrun.

9 Ṣugbọn nigbati ọkàn awọn miran ninu wọn di lile, ti nwọn kò si gbagbọ́, ti nwọn nsọ̀rọ ibi si Ọna na niwaju ijọ enia, o lọ kuro lọdọ wọn, o si yà awọn ọmọ-ẹhin sọtọ̀, o si nsọ asọye li ojojumọ́ ni ile-iwe Tirannu.

10 Eyi nlọ bẹ̃ fun iwọn ọdún meji; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti ngbe Asia gbọ́ ọ̀rọ Jesu Oluwa, ati awọn Ju ati awọn Hellene.

Àwọn Ọmọ Skefa

11 Ọlọrun si ti ọwọ́ Paulu ṣe iṣẹ aṣẹ akanṣe,

12 Tobẹ̃ ti a fi nmu gèle ati ibantẹ́ ara rẹ̀ tọ̀ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn.

13 Ṣugbọn awọn Ju kan alarinkiri, alẹmi-èṣu-jade, dawọle e li adabọwọ ara wọn, lati pè orukọ Jesu Oluwa si awọn ti o li ẹmi buburu, wipe, Awa fi orukọ Jesu ti Paulu nwasu fi nyin bu.

14 Awọn meje kan si wà, ọmọ ẹnikan ti a npè ni Skefa, Ju, ati olori kan ninu awọn alufa, ti nwọn ṣe bẹ̃.

15 Ẹmi buburu na si dahùn, o ni, Jesu emi mọ̀, Paulu emi si mọ̀; ṣugbọn tali ẹnyin?

16 Nigbati ọkunrin ti ẹmi buburu wà lara rẹ̀ si fò mọ́ wọn, o ba wọn dimú, o bori wọn, bẹ̃ni nwọn sá jade kuro ni ile na ni ìhoho ati ni ifarapa.

17 Ihìn yi si di mimọ̀ fun gbogbo awọn Ju ati awọn ara Hellene pẹlu ti o ṣe atipo ni Efesu; ẹ̀ru si ba gbogbo wọn, a si gbé orukọ Jesu Oluwa ga.

18 Ọ̀pọ awọn ti nwọn gbagbọ́ si wá, nwọn jẹwọ, nwọn si fi iṣẹ wọn hàn.

19 Kì isi ṣe diẹ ninu awọn ti nṣe àlúpàyídà li o kó iwe wọn jọ, nwọn dáná sun wọn loju gbogbo enia: nwọn si ṣírò iye wọn, nwọn si ri i, o jẹ ẹgbã-mẹdọgbọ̀n iwọn fadaka.

20 Bẹ̃li ọ̀rọ Oluwa si gbilẹ si i gidigidi, o si gbilẹ.

Ìrúkèrúdò Bẹ́ Sílẹ̀ ní Efesu

21 Njẹ bi nkan wọnyi ti pari tan, Paulu pinnu rẹ̀ li ọkàn pe, nigbati on ba kọja ni Makedonia ati Akaia, on ó lọ si Jerusalemu, o wipe, Lẹhin igba ti mo ba de ibẹ̀, emi kò le ṣaima ri Romu pẹlu.

22 Nigbati o si ti rán meji ninu awọn ti nṣe iranṣẹ fun u lọ si Makedonia, Timotiu ati Erastu, on tikararẹ̀ duro ni Asia ni igba diẹ na.

23 Li akokò na èmìmì diẹ ki o wà nitori Ọna na.

24 Nitori ọkunrin kan ti a npè ni Demetriu, alagbẹdẹ fadaka, ti ima fi fadaka ṣe ile-oriṣa fun Diana, o mu ère ti kò mọ̀ ni iwọn fun awọn oniṣọnà wá;

25 Nigbati o pè wọn jọ, ati irú awọn ọlọnà bẹ̃, o ni, Alàgba, ẹnyin mọ̀ pe nipa iṣẹ-ọna yi li awa fi li ọrọ̀ wa.

26 Ẹnyin si ri, ẹ si gbọ́ pe, kì iṣe ni Efesu nikanṣoṣo ni, ṣugbọn o fẹrẹ ṣe gbogbo Asia, ni Paulu yi nyi ọ̀pọ enia li ọkàn pada, ti o si ndari wọn wipe, Ohun ti a fi ọwọ́ ṣe, kì iṣe ọlọrun.

27 Ki si iṣe pe kìki iṣẹ-ọnà wa yi li o wà li ewu ati di asan; ṣugbọn ile Diana oriṣa nla yio si di gigàn pẹlu, ati gbogbo ọla nla rẹ̀ yio si run, ẹniti gbogbo Asia ati gbogbo aiye mbọ.

28 Nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn kún fun ibinu, nwọn kigbe, wipe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu.

29 Gbogbo ilu na si kún fun irukerudò: nwọn fi ọkàn kan rọ́ sinu ile ibĩṣire, nwọn si mu Gaiu ati Aristarku ara Makedonia, awọn ẹgbẹ ajọrin Paulu.

30 Nigbati Paulu si nfẹ wọ̀ ãrin awọn enia lọ, awọn ọmọ-ẹhin kò jẹ fun u.

31 Awọn olori kan ara Asia, ti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ranṣẹ si i, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe fi ara rẹ̀ wewu ninu ile ibiṣire.

32 Njẹ awọn kan nwi ohun kan, awọn miran nwi omiran: nitori ajọ di rudurudu; ati ọ̀pọ enia ni kò mọ̀ itori ohun ti nwọn tilẹ fi wọjọ pọ̀ si.

33 Nwọn si fà Aleksanderu kuro li awujọ, awọn Ju tì i ṣaju. Aleksanderu si juwọ́ si wọn, on iba si wi ti ẹnu rẹ̀ fun awọn enia.

34 Ṣugbọn nigbati nwọn mọ̀ pe Ju ni, gbogbo wọn li ohùn kan, niwọn wakati meji ọjọ, kigbe pe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu.

35 Nigbati akọwe ilu si mu ki ijọ enia dakẹ, o ni, Ẹnyin ará Efesu, tali ẹniti o wà ti kò mọ̀ pe, ilu ara Efesu ni iṣe olusin Diana oriṣa nla, ati ti ere ti o ti ọdọ Jupiteri bọ́ silẹ?

36 Njẹ bi a ko ti le sọrọ odi si nkan wọnni, o yẹ ki ẹ dakẹ, ki ẹnyin ki o máṣe fi iwara ṣe ohunkohun.

37 Nitoriti ẹnyin mu awọn ọkunrin wọnyi wá, nwọn kò kó ile oriṣa, bẹ̃ni nwọn kò sọrọ-odi si oriṣa wa.

38 Njẹ nitorina bi Demetriu, ati awọn oniṣọnà ti o wà pẹlu rẹ̀, ba li ọ̀rọ kan si ẹnikẹni, ile-ẹjọ ṣí silẹ, awọn onidajọ si mbẹ: jẹ ki nwọn ki o lọ ifi ara wọn sùn.

39 Ṣugbọn bi ẹ ba nwadi ohun kan nipa ọ̀ran miran, a ó pari rẹ̀ ni ajọ ti o tọ́.

40 Nitori awa sá wà li ewu ati pè bi lẽrè nitori ariwo oni yi, kò sa nidi, ati nitori eyi awa kì yio le dahun fun iwọjọ yi.

41 Nigbati o si ti sọ bẹ̃ tan, o tú ijọ na ká.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28