Iṣe Apo 22 YCE

1 ẸNYIN ará, ati baba, ẹ gbọ ti ẹnu mi nisisiyi.

2 (Nigbati nwọn si gbọ́ pe o mba wọn sọrọ li ede Heberu, nwọn tubọ parọrọ; o si wipe,)

3 Ju li emi iṣe ẹniti a bí ni Tarsu ilu kan ni Kilikia, ṣugbọn ti a tọ́ ni ilu yi, li ẹsẹ Gamalieli, ti a kọ́ gẹgẹ bi lile ofin awọn baba wa, ti mo si jẹ onitara fun Ọlọrun ani gẹgẹ bi gbogbo nyin ti ri li oni.

4 Mo si ṣe inunibini si Ọna yi titi o fi de iku, mo ndè, mo si nfi wọn sinu tubu, ati ọkunrin ati obinrin.

5 Bi olori alufa pẹlu ti jẹ mi li ẹri, ati gbogbo ajọ awọn alàgba: lọwọ awọn ẹniti mo si gbà iwe lọ sọdọ awọn arakunrin, ti mo si lọ si Damasku lati mu awọn ti o wà nibẹ̀ ni didè wá si Jerusalemu, lati jẹ wọn niyà.

Paulu Sọ Bí Ó Ṣe Di Onigbagbọ

6 O si ṣe, bi emi ti nlọ, ti mo si sunmọ eti Damasku niwọn ọjọkanri, li ojijì, imọlẹ nla mọ́ ti ọrun wá yi mi ká.

7 Mo si ṣubu lùlẹ, mo si ngbọ́ ohùn kan ti o wi fun mi pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi?

8 Emi si dahùn wipe, Iwọ tani, Oluwa? O si wi fun mi pe, Emi Jesu ti Nasareti ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si.

9 Awọn ti o si wà pẹlu mi ri imọlẹ na nitõtọ, ẹ̀ru si ba wọn; ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ohùn ẹniti mba mi sọrọ.

10 Mo si wipe, Kini ki emi ki o ṣe, Oluwa? Oluwa si wi fun mi pe, Dide, ki o si lọ si Damasku; nibẹ̀ li a o si sọ ohun gbogbo fun ọ ti a yàn fun ọ lati ṣe.

11 Bi emi kò si ti le riran nitori itànṣan imọlẹ na, a ti ọwọ́ awọn ti o wà lọdọ mi fà mi, mo si de Damasku.

12 Ẹnikan si tọ̀ mi wá, Anania, ọkunrin olufọkansìn gẹgẹ bi ofin, ti o li orukọ rere lọdọ gbogbo awọn Ju ti o ngbe ibẹ̀.

13 O si duro tì mi, o si wi fun mi pe, Saulu arakunrin, riran. Ni wakati kanna mo si ṣiju soke wò o.

14 O si wipe, Ọlọrun awọn baba wa yàn ọ, lati mọ̀ ifẹ rẹ̀, ati lati ri Olõtọ nì, ati lati gbọ́ ohùn li ẹnu rẹ̀,

15 Ki iwọ ki o le ṣe ẹlẹri rẹ̀ fun gbogbo enia, li ohun ti iwọ ti ri ti iwọ si ti gbọ́.

16 Njẹ nisisiyi kini iwọ nduro de? Dide, ki a si baptisi rẹ, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ nù, ki o si mã pè orukọ Oluwa.

A rán Paulu sí Àwọn tí Kì í Ṣe Juu

17 O si ṣe pe, nigbati mo pada wá si Jerusalemu, ti mo ngbadura ni tẹmpili mo bọ si ojuran;

18 Mo si ri i, o wi fun mi pe, Yara, ki o si jade kuro ni Jerusalemu kánkán: nitori nwọn kì yio gbà ẹrí rẹ nipa mi.

19 Emi si wipe, Oluwa, awọn pãpã mọ̀ pe, emi a ti mã sọ awọn ti o gbà ọ gbọ sinu tubu, emi a si mã lù wọn ninu sinagogu gbogbo:

20 Nigbati a si ta ẹ̀jẹ Stefanu ẹlẹri rẹ silẹ, emi na pẹlu duro nibẹ̀, mo si li ohùn si ikú rẹ̀, mo si nṣe itọju aṣọ awọn ẹniti o pa a.

21 O si wi fun mi pe, Mã lọ: nitori emi ó rán ọ si awọn Keferi lokere réré.

Paulu ati Ọ̀gágun Ọmọ Ìbílẹ̀ Romu

22 Nwọn si fi etí si i titi de ọ̀rọ yi, nwọn si gbé ohùn wọn soke wipe, Ẹ mu irú eyiyi kuro li aiye: nitori kò yẹ ki o wà lãye.

23 Bi nwọn si ti nkigbe, ti nwọn si wọ́n aṣọ wọn silẹ, ti nwọn nku ekuru si oju ọrun,

24 Olori ogun paṣẹ pe ki a mu u wá sinu ile-olodi, o ni ki a fi ẹgba bi i lẽre; ki on ki o le mọ̀ itori ohun ti nwọn ṣe nkigbe le e bẹ̃.

25 Bi nwọn si ti fi ọsán dè e, Paulu bi balogun ọrún ti o duro tì i pe, O ha tọ́ fun nyin lati nà ẹniti iṣe ará Romu li aijẹbi?

26 Nigbati balogun ọrún si gbọ́, o lọ, o wi fun olori-ogun pe, Kili o fẹ ṣe yi: nitori ọkunrin yi ara Romu ni iṣe.

27 Olori-ogun si de, o si bi i pe, Sọ fun mi, ara Romu ni iwọ iṣe? O si wipe, Bẹ̃ni.

28 Olori-ogun si dahùn wipe, Owo pupọ ni mo fi rà ọlá ibilẹ yi. Paulu si wipe, Ṣugbọn a bí emi bẹ̃ ni.

29 Nitorina awọn ti o mura lati bi i lẽre kuro lọdọ rẹ̀: lojukanna olori-ogun pẹlu si bẹ̀ru, nigbati o mọ̀ pe ara Romu ni iṣe, ati nitori o ti dè e.

Paulu Lọ Siwaju Àwọn Ìgbìmọ̀ Juu

30 Ni ijọ keji, nitoriti o fẹ mọ̀ dajudaju ohun ti awọn Ju nfi i sùn si, o tú u silẹ, o paṣẹ ki awọn olori alufa ati gbogbo igbimọ pejọ, o si mu Paulu sọkalẹ, o si mu u duro niwaju wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28