Iṣe Apo 14 YCE

Iṣẹ́ Paulu ati Barnaba ní Ikonioni

1 O si ṣe, ni Ikonioni, nwọn jumọ wọ̀ inu sinagogu awọn Ju lọ, nwọn si sọrọ tobẹ̃, ti ọ̀pọlọpọ awọn Ju ati awọn Hellene gbagbọ́.

2 Ṣugbọn awọn alaigbagbọ́ Ju rú ọkàn awọn Keferi soke, nwọn si rọ̀ wọn si awọn arakunrin na.

3 Nitorina nwọn gbe ibẹ̀ pẹ, nwọn nfi igboiya sọrọ ninu Oluwa, ẹniti o jẹri si ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, o si nyọnda ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu mã ti ọwọ́ wọn ṣe.

4 Ṣugbọn ọ̀pọ enia ilu na pin meji: apakan si dàpọ mọ́ awọn Ju, apakan si dàpọ mọ́ awọn aposteli.

5 Bi awọn Keferi, ati awọn Ju pẹlu awọn olori wọn ti fẹ kọlù wọn lati ṣe àbuku si wọn, ati lati sọ wọn li okuta,

6 Nwọn mọ̀, nwọn si sá lọ si Listra ati Derbe ilu Likaonia, ati si àgbegbe ti o yiká:

7 Nibẹ̀ ni nwọn si nwasu ihinrere.

Iṣẹ́ Paulu ati Barnaba ní Listra

8 Ọkunrin kan si joko ni Listra, ẹniti ẹsẹ rẹ̀ kò mokun, arọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti kò rìn ri.

9 Ọkunrin yi gbọ́ bi Paulu ti nsọ̀rọ: ẹni, nigbati o tẹjumọ́ ọ, ti o si ri pe, o ni igbagbọ́ fun imularada,

10 O wi fun u li ohùn rara pe, Dide duro ṣanṣan li ẹsẹ rẹ. O si nfò soke o si nrìn.

11 Nigbati awọn enia si ri ohun ti Paulu ṣe, nwọn gbé ohùn wọn soke li ède Likaonia, wipe, Awọn oriṣa sọkalẹ tọ̀ wa wá ni àwọ enia.

12 Nwọn si pè Barnaba ni Jupiteri ati Paulu ni Herme nitori on li olori ọ̀rọ isọ.

13 Alufa Jupiteri ti ile oriṣa rẹ̀ wà niwaju ilu wọn, si mu malu ati màriwo wá si ẹnubode, on iba si rubọ pẹlu awọn enia.

14 Ṣugbọn nigbati awọn aposteli Barnaba on Paulu gbọ́, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si sure wọ̀ inu awujọ, nwọn nke rara.

15 Nwọn si nwipe, Ará, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe nkan wọnyi? Enia oniru ìwa kanna bi ẹnyin li awa pẹlu ti a nwasu ihinrere fun nyin, ki ẹnyin ki o yipada kuro ninu ohun asan wọnyi si Ọlọrun alãye, ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn:

16 Ẹni, ni awọn iran ti o ti kọja jọwọ gbogbo orilẹ-ède, lati mã rìn li ọna tiwọn.

17 Ṣugbọn ko fi ara rẹ̀ silẹ li ailẹri, ni ti o nṣe rere, o nfun nyin ni òjo lati ọrun wá, ati akokò eso, o nfi onjẹ ati ayọ̀ kún ọkàn nyin.

18 Diẹ li o kù ki nwọn ki o ma le fi ọ̀rọ wọnyi da awọn enia duro, ki nwọn ki o máṣe rubọ bọ wọn.

19 Awọn Ju kan si ti Antioku ati Ikonioni wá, nigbati nwọn yi awọn enia li ọkàn pada, nwọn si sọ Paulu li okuta, nwọn wọ́ ọ jade kuro ni ilu na, nwọn ṣebi o kú.

20 Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin duro tì i yiká, o dide, o si wọ̀ ilu na lọ: ni ijọ keji o ba Barnaba lọ si Derbe.

21 Nigbati nwọn si ti wasu ihinrere fun ilu na, ti nwọn si ni ọmọ-ẹ̀hin pupọ, nwọn pada lọ si Listra, ati Ikonioni, ati si Antioku.

22 Nwọn nmu awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le, nwọn ngbà wọn niyanju lati duro ni igbagbọ́, ati pe ninu ipọnju pipọ li awa o fi wọ̀ ijọba Ọlọrun.

23 Nigbati nwọn si ti yàn awọn àgbagba fun olukuluku ijọ, ti nwọn si ti fi àwẹ gbadura, nwọn fi wọn le Oluwa lọwọ, ẹniti nwọn gbagbọ́.

24 Nigbati nwọn si là Pisidia já, nwọn wá si Pamfilia.

25 Nigbati nwọn si ti sọ ọ̀rọ na ni Perga, nwọn sọkalẹ lọ si Atalia:

26 Ati lati ibẹ̀ lọ nwọn ba ti ọkọ̀ lọ si Antioku, lati ibiti a gbé ti fi wọn le õre-ọfẹ Ọlọrun lọwọ, fun iṣẹ ti nwọn ṣe pari.

27 Nigbati nwọn si de, ti nwọn si pè ijọ jọ, nwọn ròhin gbogbo ohun ti Ọlọrun fi wọn ṣe, ati bi o ti ṣí ilẹkun igbagbọ́ fun awọn Keferi.

28 Ki iṣe igba diẹ ni nwọn ba awọn ọmọ-ẹhin gbé.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28