33 Nitorina ni mo si ti ranṣẹ si ọ lojukanna, iwọ si ṣeun ti o fi wá. Gbogbo wa pé niwaju Ọlọrun nisisiyi, lati gbọ́ ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun ọ lati ọdọ Ọlọrun wá.
34 Peteru si yà ẹnu rẹ̀, o si wipe, Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun kì iṣe ojuṣaju enia:
35 Ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ède, ẹniti o ba bẹ̀ru rẹ̀, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀.
36 Ọ̀rọ ti Ọlọrun rán si awọn ọmọ Israeli, nigbati o wasu alafia nipa Jesu Kristi (on li Oluwa ohun gbogbo),
37 Ẹnyin na mọ̀ ọ̀rọ na ti a kede rẹ̀ yiká gbogbo Judea, ti a bẹ̀rẹ si lati Galili wá, lẹhin baptismu ti Johanu wasu rẹ̀;
38 Ani Jesu ti Nasareti, bi Ọlọrun ti dà Ẹmi Mimọ́ ati agbara le e lori: ẹniti o nkiri ṣe ore, nṣe didá ara gbogbo awọn ti Èṣu si npọn loju; nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.
39 Awa si li ẹlẹri gbogbo ohun ti o ṣe, ni ilẹ awọn Ju, ati ni Jerusalemu; ẹniti nwọn pa, ti nwọn si fi gbékọ sori igi: