13 O si sọ fun wa bi on ti ri angẹli kan ti o duro ni ile rẹ̀, ti o si wipe, Ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni ti apele rẹ̀ jẹ Peteru;
14 Ẹniti yio sọ ọ̀rọ fun ọ, nipa eyiti a o fi gbà iwọ ati gbogbo ile rẹ là.
15 Bi mo si ti bẹ̀rẹ si isọ, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn, gẹgẹ bi o ti bà le wa li àtetekọṣe.
16 Nigbana ni mo ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wipe, Johanu fi omi baptisi nitõtọ; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin.
17 Njẹ bi Ọlọrun si ti fi iru ẹ̀bun kanna fun wọn ti o ti fifun awa pẹlu nigbati a gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, tali emi ti emi ó fi le dè Ọlọrun li ọ̀na?
18 Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́, nwọn si yìn Ọlọrun logo wipe, Njẹ Ọlọrun fi ironupiwada si ìye fun awọn Keferi pẹlu.
19 Nitorina awọn ti a si tuka kiri niti inunibini ti o ṣẹ̀ niti Stefanu, nwọn rìn titi de Fenike, ati Kipru, ati Antioku, nwọn kò sọ ọ̀rọ na fun ẹnikan, bikoṣe fun kìki awọn Ju.