12 Nigbati bãlẹ ri ohun ti o ṣe, o gbagbọ́, ẹnu si yà a si ẹkọ́ Oluwa.
13 Nigbati Paulu ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si ṣikọ̀ ni Pafo, nwọn wá si Perga ni Pamfilia: Johanu si fi wọn silẹ, o si pada lọ si Jerusalemu.
14 Nigbati nwọn si là Perga kọja, nwọn wá si Antioku ni Pisidia, nwọn si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ isimi, nwọn si joko.
15 Ati lẹhin kìka iwe ofin ati iwe awọn woli, awọn olori sinagogu ranṣẹ si wọn, pe, Ará, bi ẹnyin ba li ọ̀rọ iyanju kan fun awọn enia, ẹ sọ ọ.
16 Paulu si dide duro, o si juwọ́ si wọn, o ni, Ẹnyin enia Israeli, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ẹ fi etí silẹ.
17 Ọlọrun awọn enia Israeli yi, yàn awọn baba wa, o si gbé awọn enia na leke, nigbati nwọn ṣe atipo ni ilẹ Egipti, apá giga li o si fi mu wọn jade kuro ninu rẹ̀.
18 Ni ìwọn igba ogoji ọdún li o fi mu sũru fun ìwa wọn ni ijù.