3 Nitorina nwọn gbe ibẹ̀ pẹ, nwọn nfi igboiya sọrọ ninu Oluwa, ẹniti o jẹri si ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, o si nyọnda ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu mã ti ọwọ́ wọn ṣe.
4 Ṣugbọn ọ̀pọ enia ilu na pin meji: apakan si dàpọ mọ́ awọn Ju, apakan si dàpọ mọ́ awọn aposteli.
5 Bi awọn Keferi, ati awọn Ju pẹlu awọn olori wọn ti fẹ kọlù wọn lati ṣe àbuku si wọn, ati lati sọ wọn li okuta,
6 Nwọn mọ̀, nwọn si sá lọ si Listra ati Derbe ilu Likaonia, ati si àgbegbe ti o yiká:
7 Nibẹ̀ ni nwọn si nwasu ihinrere.
8 Ọkunrin kan si joko ni Listra, ẹniti ẹsẹ rẹ̀ kò mokun, arọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti kò rìn ri.
9 Ọkunrin yi gbọ́ bi Paulu ti nsọ̀rọ: ẹni, nigbati o tẹjumọ́ ọ, ti o si ri pe, o ni igbagbọ́ fun imularada,