37 Ṣugbọn Paulu wi fun wọn pe, Nwọn lù wa ni gbangba, nwọn si sọ wa sinu tubu li aijẹbi, awa ẹniti iṣe ara Romu: nisisiyi nwọn si fẹ ti wa jade nikọ̀kọ? agbẹdọ; ṣugbọn ki awọn tikarawọn wá mu wa jade.
38 Awọn ọlọpa si sọ ọrọ wọnyi fun awọn onidajọ: ẹ̀ru si bà wọn, nigbati nwọn gbọ́ pe ara Romu ni nwọn.
39 Nwọn si wá, nwọn ṣìpẹ fun wọn, nwọn si mu wọn jade, nwọn si bẹ̀ wọn pe, ki nwọn ki o jade kuro ni ilu na.
40 Nwọn si jade ninu tubu, nwọn si wọ̀ ile Lidia lọ: nigbati nwọn si ti ri awọn arakunrin, nwọn tù wọn ninu, nwọn si jade kuro.