11 Nigbati o si tún gòke lọ, ti o si bù akara, ti o si jẹ, ti o si sọ̀rọ pẹ titi o fi di afẹmọjumọ́, bẹ̃li o lọ.
12 Nwọn si mu ọmọkunrin na bọ̀ lãye, inu nwọn si dun gidigidi.
13 Nigbati awa si ṣaju, awa si ṣikọ̀ lọ si Asso, nibẹ̀ li a nfẹ gbà Paulu si ọkọ̀: nitori bẹ̃li o ti pinnu rẹ̀, on tikararẹ̀ nfẹ ba ti ẹsẹ lọ.
14 Nigbati o pade wa ni Asso, ti a si ti gbà a si ọkọ̀, a lọ si Mitilene.
15 Nigbati a si ṣikọ̀ nibẹ̀, ni ijọ keji a de ọkankan Kio; ni ijọ keji rẹ̀ a de Samo, a si duro ni Trogillioni; ni ijọ keji rẹ̀ a si de Miletu.
16 Paulu sá ti pinnu rẹ̀ lati mu ọkọ̀ lọ niha Efesu, nitori ki o ma ba fi igba na joko ni Asia: nitori o nyára bi yio ṣe iṣe fun u, lati wà ni Jerusalemu li ọjọ Pentikosti.
17 Ati lati Miletu o ranṣẹ si Efesu, lati pè awọn alàgba ijọ wá sọdọ rẹ̀.