18 Ni ijọ keji awa ba Paulu lọ sọdọ Jakọbu; gbogbo awọn alàgba si wà nibẹ̀.
19 Nigbati o si kí wọn tan, o ròhin ohun gbogbo lẹsẹsẹ ti Ọlọrun ṣe lãrin awọn Keferi nipa iṣẹ-iranṣẹ rẹ̀.
20 Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn yin Ọlọrun logo, nwọn si wi fun u pe, Arakunrin, iwọ ri iye ẹgbẹgbẹrun ninu awọn Ju ti o gbagbọ, gbogbo nwọn li o si ni itara fun ofin.
21 Nwọn si ti ròhin rẹ fun wọn pe, Iwọ nkọ́ gbogbo awọn Ju ti o wà lãrin awọn Keferi pe, ki nwọn ki o kọ̀ Mose silẹ, o si nwi fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe kọ awọn ọmọ wọn ni ilà mọ́, ati ki nwọn ki o máṣe rìn gẹgẹ bi àṣa wọn.
22 Njẹ ewo ni ṣiṣe? ijọ kò le ṣaima pejọ pọ̀: dajudaju nwọn ó gbọ́ pe, iwọ de.
23 Njẹ eyi ti awa ó wi fun ọ yi ni ki o ṣe: Awa li ọkunrin mẹrin ti nwọn ni ẹ̀jẹ́ lara wọn;
24 Awọn ni ki iwọ ki o mu, ki o si ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn ki o si ṣe inawo wọn, ki nwọn ki o le fá ori wọn: gbogbo enia yio si mọ̀ pe, kò si otitọ kan ninu ohun ti nwọn gbọ si ọ; ṣugbọn pe, iwọ tikararẹ nrìn dede pẹlu, iwọ si npa ofin mọ́.