26 Nigbana ni Paulu mu awọn ọkunrin na; ni ijọ keji o ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn, o si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o sọ ìgba ti ọjọ ìwẹ̀numọ́ na yio pé titi a fi rubọ fun olukuluku wọn.
27 Nigbati ọjọ meje si fẹrẹ pé, ti awọn Ju ti o ti Asia wa ri i ni tẹmpili, nwọn rú gbogbo awọn enia soke, nwọn nawọ́ mu u.
28 Nwọn nkigbe wipe, Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbà wa: Eyi li ọkunrin na, ti nkọ́ gbogbo enia nibigbogbo lòdi si awọn enia, ati si ofin, ati si ibi yi: ati pẹlu o si mu awọn ara Hellene wá si tẹmpili, o si ti ba ibi mimọ́ yi jẹ.
29 Nitori nwọn ti ri Trofimu ará Efesu pẹlu rẹ̀ ni ilu, ẹniti nwọn ṣebi Paulu mu wá sinu tẹmpili.
30 Gbogbo ilu si rọ́, awọn enia si sure jọ: nwọn si mu Paulu, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu tẹmpili: lojukanna a si tì ilẹkun.
31 Bi nwọn si ti nwá ọ̀na ati pa a, ìhin de ọdọ olori ẹgbẹ ọmọ-ogun pe, gbogbo Jerusalemu dàrú.
32 Lojukanna o si ti mu awọn ọmọ-ogun ati awọn balogun ọrún, o si sure sọkalẹ tọ̀ wọn lọ: nigbati nwọn si ri olori ogun ati awọn ọmọ-ogun, nwọn dẹkun lilu Paulu.