21 Bikoṣe ti gbolohùn kan yi, ti mo ke nigbati mo duro li ãrin wọn, Nitori ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ lọdọ nyin loni yi.
22 Nigbati Feliksi gbọ́ nkan wọnyi, oye sa ye e li ayetan nipa Ọna na; o tú wọn ká na, o ni, Nigbati Lisia olori ogun ba sọkalẹ wá, emi o wadi ọ̀ran nyin daju.
23 O si paṣẹ fun balogun ọrún kan pe, ki o mã ṣe itọju Paulu, ki o si bùn u làye, ati pe ki o máṣe dá awọn ojulumọ̀ rẹ̀ lẹkun, lati ma ṣe iranṣẹ fun u.
24 Ṣugbọn lẹhin ijọ melokan, Feliksi de ti on ti Drusilla obinrin rẹ̀, ti iṣe Ju, o si ranṣẹ pè Paulu, o si gbọ́ ọ̀rọ lọdọ rẹ̀ nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.
25 Bi o si ti nsọ asọye nipa ti ododo ati airekọja ati idajọ ti mbọ̀, ẹ̀ru ba Feliksi, o dahùn wipe, Mã lọ nisisiyi na; nigbati mo ba si ni akokò ti o wọ̀, emi o ranṣẹ pè ọ.
26 O si nreti pẹlu pe a ba fun on li owo lati ọwọ́ Paulu wá, ki on ki o le da a silẹ: nitorina a si ma ranṣẹ si i nigbakugba, a ma ba a sọ̀rọ.
27 Ṣugbọn lẹhin ọdún meji, Porkiu Festu rọpò Feliksi: Feliksi si nfẹ ṣe oju're fun awọn Ju, o fi Paulu silẹ li ondè.