24 Festu si wipe, Agrippa ọba, ati gbogbo ẹnyin enia ti o wà nihin pẹlu wa, ẹnyin ri ọkunrin yi, nitori ẹniti gbogbo ijọ awọn Ju ti rọgbaká mi, ni Jerusalemu ati nihinyi, ti nwọn nkigbe pe, Kò yẹ fun u lati wà lãye mọ́.
25 Ṣugbọn emi ri pe, kò ṣe ohun kan ti o yẹ si ikú, bi on tikararẹ̀ si ti fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, mo ti pinnu lati rán a lọ.
26 Nipasẹ ẹniti emi kò ri ohun kan dajudaju lati kọwe si oluwa mi. Nitorina ni mo ṣe mu u jade wá siwaju nyin, ati pe siwaju rẹ, Agrippa ọba, pãpã lẹhin ti a ba ti wadi rẹ̀, ki emi ki o le ri ohun ti emi ó kọ.
27 Nitoriti kò tọ́ li oju mi lati rán ondè, ki a má si sọ ọ̀ran ti a kà si i lọrùn.