4 Ṣugbọn Festu dahun pe, a pa Paulu mọ́ ni Kesarea, ati pe on tikara on nmura ati pada lọ ni lọ̃lọ̃yi.
5 O ni, njẹ awọn ti o ba to ninu nyin, ki nwọn ba mi sọkalẹ lọ, bi ìwa buburu kan ba wà lọwọ ọkunrin yi, ki nwọn ki o fi i sùn.
6 Kò si gbe ãrin wọn ju ijọ mẹjọ tabi mẹwa lọ, o sọkalẹ lọ si Kesarea; ni ijọ keji o joko lori itẹ́ idajọ, o si paṣẹ pè ki a mu Paulu wá.
7 Nigbati o si de, awọn Ju ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá duro yi i ká, nwọn nkà ọ̀ran pipọ ti o si buru si Paulu lọrùn, ti nwọn kò le ladi.
8 Paulu si wi ti ẹnu rẹ̀ pe, Emi kò ṣẹ ẹṣẹkẹṣẹ kan si ofin awọn Ju, tabi si tẹmpili, tabi si Kesari.
9 Ṣugbọn Festu nfẹ gbà oju're lọdọ awọn Ju, o si da Paulu lohùn, wipe, Iwọ ha nfẹ goke lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀ niwaju mi bi?
10 Paulu si wipe, Niwaju itẹ́ idajọ Kesari ni mo duro nibiti o yẹ ki a ṣe ẹjọ mi: emi kò ṣẹ awọn Ju, bi iwọ pẹlu ti mọ̀ daju.