1 AGRIPPA si wi fun Paulu pe, A fun ọ làye lati sọ ti ẹnu rẹ. Nigbana ni Paulu nawọ́, o si sọ ti ẹnu rẹ̀ pe:
2 Agrippa ọba, inu emi tikarami dùn nitoriti emi o wi ti ẹnu mi loni niwaju rẹ, niti gbogbo nkan ti awọn Ju nfi mi sùn si.
3 Pãpã bi iwọ ti mọ̀ gbogbo iṣe ati ọ̀ran ti mbẹ lãrin awọn Ju dajudaju, nitorina emi bẹ̀ ọ ki iwọ ki o fi sũru gbọ temi.
4 Iwà aiye mi lati igba ewe mi, bi o ti ri lati ibẹrẹ, lãrin orilẹ-ede mi ati ni Jerusalemu, ni gbogbo awọn Ju mọ̀.