19 Nitorina, Agrippa ọba, emi kò ṣe aigbọran si iran ọ̀run na.
20 Ṣugbọn mo kọ́ sọ fun awọn ti o wà ni Damasku, ati ni Jerusalemu, ati já gbogbo ilẹ Judea, ati fun awọn Keferi, ki nwọn ki o ronupiwada, ki nwọn si yipada si Ọlọrun, ki nwọn mã ṣe iṣẹ ti o yẹ si ironupiwada.
21 Nitori nkan wọnyi li awọn Ju ṣe mu mi ni tẹmpili, ti nwọn si fẹ pa mi.
22 Ṣugbọn bi mo si ti ri iranlọwọ gbà lọdọ Ọlọrun, mo duro titi o fi di oni, mo njẹri fun ati ewe ati àgba, emi kò sọ ohun miran bikoṣe ohun ti awọn woli ati Mose ti wipe yio ṣẹ:
23 Pe, Kristi yio jìya, ati pe nipa ajinde rẹ̀ kuro ninu oku, on ni yio kọ́ kede imọlẹ fun awọn enia ati fun awọn Keferi.
24 Bi o si ti nsọ t'ẹnu rẹ̀, Festu wi li ohùn rara pe, Paulu, ori rẹ bajẹ; ẹkọ́ akọjù ba ọ li ori jẹ.
25 Ṣugbọn Paulu wipe, Ori mi kò bajẹ, Festu ọlọlá julọ; ṣugbọn ọ̀rọ otitọ ati ti ìwa airekọja li emi nsọ jade.