1 BI nwọn si ti mba awọn enia sọrọ, awọn alufa ati olori ẹṣọ́ tẹmpili ati awọn Sadusi dide si wọn.
2 Inu bi wọn, nitoriti nwọn nkọ́ awọn enia, nwọn si nwasu ajinde kuro ninu okú ninu Jesu.
3 Nwọn si nawọ́ mu wọn, nwọn si há wọn mọ́ ile tubu titi o fi di ijọ keji: nitoriti alẹ lẹ tan.
4 Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na gbagbọ́; iye awọn ọkunrin na si to ẹgbẹ̃dọgbọn.