2 Inu bi wọn, nitoriti nwọn nkọ́ awọn enia, nwọn si nwasu ajinde kuro ninu okú ninu Jesu.
3 Nwọn si nawọ́ mu wọn, nwọn si há wọn mọ́ ile tubu titi o fi di ijọ keji: nitoriti alẹ lẹ tan.
4 Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na gbagbọ́; iye awọn ọkunrin na si to ẹgbẹ̃dọgbọn.
5 O si ṣe nijọ keji, awọn olori wọn ati awọn alagba ati awọn akọwe, pejọ si Jerusalemu,
6 Ati Anna olori alufa, ati Kaiafa, ati Johanu, ati Aleksanderu, ati iye awọn ti iṣe ibatan olori alufa.
7 Nigbati nwọn si mu wọn duro li ãrin, nwọn bère pe, Agbara tabi orukọ wo li ẹnyin fi ṣe eyi?
8 Nigbana ni Peteru kún fun Ẹmí Mimọ́, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin olori awọn enia, ati ẹnyin àgbagbà.