4 Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na gbagbọ́; iye awọn ọkunrin na si to ẹgbẹ̃dọgbọn.
5 O si ṣe nijọ keji, awọn olori wọn ati awọn alagba ati awọn akọwe, pejọ si Jerusalemu,
6 Ati Anna olori alufa, ati Kaiafa, ati Johanu, ati Aleksanderu, ati iye awọn ti iṣe ibatan olori alufa.
7 Nigbati nwọn si mu wọn duro li ãrin, nwọn bère pe, Agbara tabi orukọ wo li ẹnyin fi ṣe eyi?
8 Nigbana ni Peteru kún fun Ẹmí Mimọ́, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin olori awọn enia, ati ẹnyin àgbagbà.
9 Bi o ba ṣe pe a nwadi wa loni niti iṣẹ rere ti a ṣe lara abirùn na, bi a ti ṣe mu ọkunrin yi laradá;
10 Ki eyi ki o yé gbogbo nyin ati gbogbo enia Israeli pe, li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, ti Ọlọrun gbé dide kuro ninu okú, nipa rẹ̀ li ọkunrin yi fi duro niwaju nyin ni dida ara ṣaṣa.