23 Awa bá ile tubu o sé pinpin, ati awọn oluṣọ duro lode niwaju ilẹkun: ṣugbọn nigbati awa ṣílẹkun, awa kò bá ẹnikan ninu tubu.
24 Nigbati olori ẹṣọ́ tẹmpili ati awọn olori alufa si gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn dãmu nitori wọn pe, nibo li eyi ó yọri si.
25 Nigbana li ẹnikan de, o wi fun wọn pe, Wo o, awọn ọkunrin ti ẹnyin fi sinu tubu wà ni tẹmpili, nwọn duro nwọn si nkọ́ awọn enia.
26 Nigbana li olori ẹṣọ́ lọ pẹlu awọn onṣẹ, o si mu wọn wá kì iṣe pẹlu ipa: nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn enia, ki a má ba sọ wọn li okuta.
27 Nigbati nwọn si mu wọn de, nwọn mu wọn duro niwaju ajọ igbimọ; olori alufa si bi wọn lẽre,
28 Wipe, Awa kò ti kìlọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yi kọ́ni mọ́? si wo o, ẹnyin ti fi ẹkọ́ nyin kún Jerusalemu, ẹ si npete ati mu ẹ̀jẹ ọkunrin yi wá si ori wa.
29 Ṣugbọn Peteru ati awọn aposteli dahùn, nwọn si wipe, Awa kò gbọdọ má gbọ́ ti Ọlọrun jù ti enia lọ.