48 Ṣugbọn Ọgá-ogo kì igbé ile ti a fi ọwọ kọ́; gẹgẹ bi woli ti wipe,
49 Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si li apoti itisẹ mi: irú ile kili ẹnyin o kọ́ fun mi? li Oluwa wi; tabi ibo ni ibi isimi mi?
50 Ọwọ́ mi kọ́ ha ṣe gbogbo nkan wọnyi?
51 Ẹnyin ọlọrùn-lile ati alaikọla àiya on etí, nigba-gbogbo li ẹnyin ima dèna Ẹmí Mimọ́: gẹgẹ bi awọn baba nyin, bẹ̃li ẹnyin.
52 Tani ninu awọn woli ti awọn baba nyin kò ṣe inunibini si? nwọn si ti pa awọn ti o ti nsọ asọtẹlẹ ti wíwa Ẹni Olõtọ nì; ẹniti ẹnyin si ti di olufihàn ati olupa:
53 Ẹnyin ti o gbà ofin, gẹgẹ bi ilana awọn angẹli, ti ẹ kò si pa a mọ́.
54 Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, àiya wọn gbọgbẹ́ de inu, nwọn si pahin si i keke.