31 O si dahùn wipe, Yio ha ṣe yé mi, bikoṣepe ẹnikan tọ́ mi si ọna? O si bẹ̀ Filippi ki o gòke wá, ki o si ba on joko.
32 Ibi iwe-mimọ́ ti o si nkà na li eyi, A fà a bi agutan lọ fun pipa; ati bi ọdọ-agutan iti iyadi niwaju olurẹrun rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀:
33 Ni irẹsilẹ rẹ̀ a mu idajọ kuro: tani yio sọ̀rọ iran rẹ̀? nitori a gbà ẹmí rẹ̀ kuro li aiye.
34 Iwẹfa si da Filippi lohùn, o ni, Mo bẹ̀ ọ, ti tani woli na sọ ọ̀rọ yi? ti ara rẹ̀, tabi ti ẹlomiran?
35 Filippi si yà ẹnu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ lati ibi iwe-mimọ́ yi, o si wasu Jesu fun u.
36 Bi nwọn si ti nlọ li ọ̀na, nwọn de ibi omi kan: iwẹfa na si wipe, Wò o, omi niyi; kili o dá mi duro lati baptisi?
37 Filippi si wipe, Bi iwọ ba gbagbọ́ tọkàntọkan, a le baptisi rẹ. O si dahùn o ni, Mo gbagbọ́ pe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun ni.