37 Filippi si wipe, Bi iwọ ba gbagbọ́ tọkàntọkan, a le baptisi rẹ. O si dahùn o ni, Mo gbagbọ́ pe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun ni.
38 O si paṣẹ ki kẹkẹ́ duro jẹ: awọn mejeji si sọkalẹ lọ sinu omi, ati Filippi ati iwẹfa; o si baptisi rẹ̀.
39 Nigbati nwọn si jade kuro ninu omi, Ẹmí Oluwa ta Filippi pá, iwẹfa kò si ri i mọ́: nitoriti o mbá ọ̀na rẹ̀ lọ, o nyọ̀.
40 Ni Asotu li a si ri Filippi; bi o si ti nkọja lọ, o nwasu ihinrere ni gbogbo ilu, titi o fi de Kesarea.