5 Filippi si sọkalẹ lọ si ilu Samaria, o nwasu Kristi fun wọn.
6 Awọn ijọ enia si fi ọkàn kan fiyesi ohun ti Filippi nsọ, nigbati nwọn ngbọ́, ti nwọn si ri iṣẹ ami ti o nṣe.
7 Nitori ọpọ ninu awọn ti o ni ẹmi àimọ́ ti nkigbe lohùn rara, jade wá, ati ọpọ awọn ti ẹ̀gba mbajà, ati awọn amọ́kún, a si ṣe dida ara wọn.
8 Ayọ̀ pipọ si wà ni ilu na.
9 Ṣugbọn ọkunrin kan wà, ti a npè ni Simoni, ti iti ima ṣe oṣó ni ilu na, ti isi mã jẹ ki ẹnu ya awọn ara Samaria, a mã wipe enia nla kan li on:
10 Ẹniti gbogbo wọn bọla fun, ati ewe ati àgba, nwipe, ọkunrin yi ni agbara Ọlọrun ti a npè ni Nla.
11 On ni nwọn si bọlá fun, nitori ọjọ pipẹ li o ti nṣe oṣó si wọn.