2 Nitoripe emi njowú lori nyin niti owú ẹni ìwa-bi-Ọlọrun: nitoriti mo ti fi nyin fun ọkọ kan, ki emi ki o le mu nyin wá bi wundia ti o mọ́ sọdọ Kristi.
3 Ṣugbọn ẹru mba mi pe, li ohunkohun, gẹgẹ bi ejò ti tàn Efa jẹ nipasẹ arekereke rẹ̀, ki a maṣe mu ero-ọkàn nyin bajẹ kuro ninu inu kan ati iwa mimọ́ nyin si Kristi.
4 Nitori bi ẹniti mbọ̀ wá ba nwãsu Jesu miran, ti awa kò ti wasu rí, tabi bi ẹnyin ba gbà ẹmí miran, ti ẹnyin kò ti gbà ri, tabi ihinrere miran, ti ẹnyin kò ti tẹwọgbà, ẹnyin iba ṣe rere lati fi ara da a.
5 Nitori mo ṣiro rẹ pe emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na.
6 Ṣugbọn bi mo tilẹ jẹ òpe li ọ̀rọ, ki iṣe ni ìmọ; ṣugbọn awa ti fihan dajudaju fun nyin lãrin gbogbo enia.
7 Tabi ẹ̀ṣẹ ni mo dá ti emi nrẹ̀ ara mi silẹ ki a le gbé nyin ga, nitoriti mo ti wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin lọfẹ?
8 Emi ja ijọ miran li ole, mo ngbà owo ki emi ki o le sìn nyin.