5 Nitori mo ṣiro rẹ pe emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na.
6 Ṣugbọn bi mo tilẹ jẹ òpe li ọ̀rọ, ki iṣe ni ìmọ; ṣugbọn awa ti fihan dajudaju fun nyin lãrin gbogbo enia.
7 Tabi ẹ̀ṣẹ ni mo dá ti emi nrẹ̀ ara mi silẹ ki a le gbé nyin ga, nitoriti mo ti wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin lọfẹ?
8 Emi ja ijọ miran li ole, mo ngbà owo ki emi ki o le sìn nyin.
9 Nigbati mo si wà pẹlu nyin, ti mo si ṣe alaini, emi kò jẹ́ ẹrù fun ẹnikẹni: nitoriti ohun ti mo ṣe alaini awọn ara ti o ti Makedonia wá fi kún u; ati ninu ohun gbogbo mo ti pa ara mi mọ́ ki emi maṣe jẹ ẹrù fun nyin, bẹ̃li emi ó si mã pa ara mi mọ́.
10 Bi otitọ Kristi ti mbẹ ninu mi, kò sí ẹniti o le da mi lẹkun iṣogo yi ni gbogbo ẹkùn Akaia.
11 Nitori kini? nitori emi kò fẹran nyin ni bi? Ọlọrun mọ̀.